Isa 64:6-9
Isa 64:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo wa si dabi ohun aimọ́, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ̀ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bi afẹfẹ. Kò si ẹniti npè orukọ rẹ, ti o si rú ara rẹ̀ soke lati di ọ mu: nitori iwọ ti pa oju rẹ mọ kuro lara wa, iwọ si ti run wa, nitori aiṣedede wa. Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ ni baba wa; awa ni amọ̀, iwọ si ni ọ̀mọ; gbogbo wa si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ. Máṣe binu kọja àla, Oluwa, ki o má si ranti aiṣedede wa titilai: kiyesi i, wò, awa bẹ̀ ọ, enia rẹ ni gbogbo wa iṣe.
Isa 64:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo wa dàbí aláìmọ́, gbogbo iṣẹ́ òdodo wa dàbí àkísà ẹlẹ́gbin. Gbogbo wa rọ bí ewé, àìdára wa sì ń fẹ́ wa lọ bí atẹ́gùn. Kò sí ẹnìkan tí ń gbadura ní orúkọ rẹ, kò sí ẹni tí ń ta ṣàṣà láti dìmọ́ ọ; nítorí pé o ti fojú pamọ́ fún wa, o sì ti pa wá tì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Sibẹsibẹ OLUWA, ìwọ ni baba wa, amọ̀ ni wá, ìwọ sì ni amọ̀kòkò; iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa. OLUWA má bínú pupọ jù, má máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wa títí lae. Jọ̀wọ́, ro ọ̀rọ̀ wa wò, nítorí pé eniyan rẹ ni gbogbo wa.
Isa 64:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́, gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin; gbogbo wa kákò bí ewé, àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò. Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú; nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Síbẹ̀síbẹ̀, OLúWA, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ OLúWA: Má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé. Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà, nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.