Isa 64:5-7
Isa 64:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ pade ẹniti nyọ̀ ti o nṣiṣẹ ododo, ti o ranti rẹ li ọ̀na rẹ: kiyesi i, iwọ binu; nitori awa ti dẹṣẹ̀; a si pẹ ninu wọn, a o ha si là? Gbogbo wa si dabi ohun aimọ́, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ̀ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bi afẹfẹ. Kò si ẹniti npè orukọ rẹ, ti o si rú ara rẹ̀ soke lati di ọ mu: nitori iwọ ti pa oju rẹ mọ kuro lara wa, iwọ si ti run wa, nitori aiṣedede wa.
Isa 64:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Ò máa ran àwọn tí ń fi inú dídùn ṣiṣẹ́ òdodo lọ́wọ́, àwọn tí wọn ranti rẹ ninu ìgbé ayé wọn, o bínú, nítorí náà a dẹ́ṣẹ̀, a ti wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa tipẹ́. Ǹjẹ́ a óo rí ìgbàlà? Gbogbo wa dàbí aláìmọ́, gbogbo iṣẹ́ òdodo wa dàbí àkísà ẹlẹ́gbin. Gbogbo wa rọ bí ewé, àìdára wa sì ń fẹ́ wa lọ bí atẹ́gùn. Kò sí ẹnìkan tí ń gbadura ní orúkọ rẹ, kò sí ẹni tí ń ta ṣàṣà láti dìmọ́ ọ; nítorí pé o ti fojú pamọ́ fún wa, o sì ti pa wá tì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa.
Isa 64:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́, tí ó rántí ọ̀nà rẹ. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn, inú bí ọ. Báwo ni a ó ṣe gbà wá là? Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́, gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin; gbogbo wa kákò bí ewé, àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò. Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú; nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.