Isa 62:3-4
Isa 62:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ o jẹ ade ogo pẹlu li ọwọ́ Oluwa, ati adé oyè ọba li ọwọ́ Ọlọrun rẹ. A ki yio pè ọ ni Ikọ̀silẹ mọ́, bẹ̃ni a ki yio pè ilẹ rẹ ni Ahoro mọ: ṣugbọn a o pè ọ ni Hefsiba: ati ilẹ rẹ ni Beula: nitori inu Oluwa dùn si ọ, a o si gbe ilẹ rẹ ni iyawo.
Isa 62:3-4 Yoruba Bible (YCE)
O óo jẹ́ adé ẹwà lọ́wọ́ OLUWA, ati fìlà oyè lọ́wọ́ Ọlọrun rẹ. A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́, “Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́, a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.” Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ, ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀.
Isa 62:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ OLúWA, adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ. Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro. Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba, àti ilẹ̀ rẹ ní Beula; nítorí OLúWA yóò yọ́nú sí ọ àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.