Isa 62:1-4
Isa 62:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORI ti Sioni emi kì yio dakẹ, ati nitori ti Jerusalemu emi kì yio simi, titi ododo rẹ̀ yio fi jade bi titan imọlẹ, ati igbala rẹ̀ bi fitila ti njó. Ati awọn Keferi yio ri ododo rẹ, ati gbogbo ọba yio ri ogo rẹ: a o si fi orukọ titun pè ọ, eyiti ẹnu Oluwa yio darukọ. Iwọ o jẹ ade ogo pẹlu li ọwọ́ Oluwa, ati adé oyè ọba li ọwọ́ Ọlọrun rẹ. A ki yio pè ọ ni Ikọ̀silẹ mọ́, bẹ̃ni a ki yio pè ilẹ rẹ ni Ahoro mọ: ṣugbọn a o pè ọ ni Hefsiba: ati ilẹ rẹ ni Beula: nitori inu Oluwa dùn si ọ, a o si gbe ilẹ rẹ ni iyawo.
Isa 62:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí Sioni, ń kò ní dákẹ́, nítorí Jerusalẹmu, ń kò ní sinmi, títí ìdáláre rẹ̀ yóo fi yọ bí ìmọ́lẹ̀, tí ìgbàlà rẹ̀ yóo sì tàn bí àtùpà. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí ìdáláre rẹ, gbogbo ọba ni yóo rí ògo rẹ; orúkọ tuntun, tí OLUWA fúnra rẹ̀ yóo sọ ọ́, ni a óo máa pè ọ́. O óo jẹ́ adé ẹwà lọ́wọ́ OLUWA, ati fìlà oyè lọ́wọ́ Ọlọrun rẹ. A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́, “Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́, a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.” Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ, ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀.
Isa 62:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́, nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu, títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀, àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí òdodo rẹ, àti gbogbo ọba ògo rẹ a ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìíràn èyí tí ẹnu OLúWA yóò fi fún un. Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ OLúWA, adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ. Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro. Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba, àti ilẹ̀ rẹ ní Beula; nítorí OLúWA yóò yọ́nú sí ọ àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.