Isa 60:4-5 - Compare All Versions

Isa 60:4-5 YBCV (Bibeli Mimọ)

Gbe oju rẹ soke yika, ki o si wò; gbogbo wọn ṣa ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá sọdọ rẹ: awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio ti ọ̀na jíjin wá, a o si tọju awọn ọmọ rẹ obinrin li ẹgbẹ rẹ. Nigbana ni iwọ o ri, oju rẹ o si mọlẹ, ọkàn rẹ yio si yipada, yio si di nla: nitori a o yi ọrọ̀ okun pada si ọ, ipá awọn Keferi yio wá sọdọ rẹ.

Isa 60:4-5 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò. Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ; àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn, àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán, ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀; ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.

Isa 60:4-5 YCE (Yoruba Bible)

Gbé ojú sókè kí o wò yíká, gbogbo wọn kó ara wọn jọ, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ; àwọn ọmọ rẹ ọkunrin yóo wá láti òkèèrè, a óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin lé apá wá. Nígbà tí o bá rí wọn, inú rẹ yóo dùn, ara rẹ óo yá gágá. Ọkàn rẹ yóo kún fún ayọ̀, nítorí pé a óo gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrọ̀ inú òkun wá sọ́dọ̀ rẹ. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo kó ọrọ̀ wọn wá fún ọ.