Isa 6:1-3
Isa 6:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọdun ti Ussiah ọba kú, emi ri Oluwa joko lori itẹ ti o ga, ti o si gbe ara soke, iṣẹti aṣọ igunwà rẹ̀ kun tempili. Awọn serafu duro loke rẹ̀: ọkọ̃kan wọn ni iyẹ mẹfa, o fi meji bò oju rẹ̀, o si fi meji bò ẹsẹ rẹ̀, o si fi meji fò. Ikini si ke si ekeji pe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun, gbogbo aiye kún fun ogo rẹ̀.
Isa 6:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọdún tí Usaya Ọba kú, mo rí OLUWA: ó jókòó lórí ìtẹ́, a gbé e ga sókè, aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. Àwọn Serafu dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ìyẹ́ mẹfa mẹfa: ó fi meji bo ojú, ó fi meji bo ẹsẹ̀, ó sì ń fi meji fò. Ekinni ń ké sí ekeji pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun; gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”
Isa 6:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”