Isa 59:15-16
Isa 59:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Otitọ kò si, ẹniti o si kuro ninu ibi o sọ ara rẹ̀ di ijẹ: Oluwa si ri i, o si buru loju rẹ̀, ti idajọ kò si. O si ri pe kò si ẹnikan, ẹnu si yà a pe onipẹ̀ kò si, nitorina apá rẹ̀ mu igbala fun u wá; ati ododo rẹ̀, on li o gbé e ró.
Isa 59:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Òtítọ́ di ohun àwátì, ẹni tí ó yàgò fún iṣẹ́ ibi fi ara rẹ̀ fún ayé mú.” OLUWA rí i pé kò sí ìdájọ́ òdodo, ó sì bà á lọ́kàn jẹ́, Ó rí i pé kò sí ẹnìkan tí yóo ṣe onílàjà, ẹnu sì yà á, pé kò sí ẹnìkankan. Ó bá fi ọwọ́ rẹ̀ ṣẹgun fún ara rẹ̀, òdodo rẹ̀ sì gbé e dúró.
Isa 59:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
A kò rí òtítọ́ mọ́, àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ. OLúWA wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ pé kò sí ìdájọ́ òdodo. Òun rí i pé kò sí ẹnìkan, àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́; nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀, àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.