Isa 58:8-11
Isa 58:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni imọlẹ rẹ yio bẹ́ jade bi owurọ, ilera rẹ yio sọ jade kánkán: ododo rẹ yio si lọ ṣaju rẹ; ogo Oluwa yio kó ọ jọ. Nigbana ni iwọ o pè, Oluwa yio si dahun; iwọ o kigbe, on o si wipe, Emi nĩ. Bi iwọ ba mu àjaga, ninà ika, ati sisọ asan, kuro lãrin rẹ. Bi iwọ ba fà ọkàn rẹ jade fun ẹniti ebi npa, ti o si tẹ́ ọkàn ti a npọ́n loju lọrùn, nigbana ni imọlẹ rẹ yio si là ninu okùnkun, ati okùnkun rẹ bi ọ̀san gangan. Oluwa yio ma tọ́ ọ nigbagbogbo, yio si tẹ́ ọkàn rẹ lọrun ni ibi gbigbẹ, yio si mu egungun rẹ sanra; iwọ o si dabi ọgbà ti a bomirin, ati bi isun omi ti omi rẹ̀ ki itán.
Isa 58:8-11 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn bí ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ara yín yóo sì tètè yá. Òdodo yín yóo máa tàn níwájú yín. Ògo mi yóo ṣe ààbò lẹ́yìn yín. Ẹ óo ké pè mí nígbà náà, n óo sì da yín lóhùn. Ẹ óo kígbe pè mí, n óo sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ “Bí ẹ bá mú àjàgà kúrò láàrin yín, tí ẹ kò fi ìka gún ara yín nímú mọ́, tí ẹ kò sì sọ ọ̀rọ̀ ibi mọ́. Bí ẹ bá ṣe làálàá láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ẹ sì wá ọ̀nà ìtẹ́lọ́rùn fún ẹni tí ìyà ń jẹ, ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn biribiri yín yóo dàbí ọ̀sán. N óo máa tọ yín sọ́nà nígbà gbogbo, n óo fi nǹkan rere tẹ yín lọ́rùn; n óo mú kí egungun yín ó le, ẹ óo sì dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, ati bí orísun omi, tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.
Isa 58:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀ àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá; nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ, ògo OLúWA yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ. Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí OLúWA yóò sì dáhùn; ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, Èmi nìyí. “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára, nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ, àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn, nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn, àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan. OLúWA yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo; òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀ yóò sì fún egungun rẹ lókun. Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára, àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.