Isa 58:13-14
Isa 58:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi iwọ ba yí ẹsẹ rẹ kuro li ọjọ isimi, lati má ṣe afẹ́ rẹ li ọjọ isimi mi; ti iwọ si pè ọjọ isimi ni adùn, ọjọ mimọ́ Oluwa, ọlọ́wọ̀; ti iwọ si bọ̀wọ fun u, ti iwọ kò hù ìwa rẹ, tabi tẹle afẹ rẹ, tabi sọ ọ̀rọ ara rẹ. Nigbana ni inu rẹ yio dùn si Oluwa, emi o si mu ọ gùn ibi giga aiye, emi o si fi ilẹ níni Jakobu baba rẹ bọ́ ọ: nitori ẹnu Oluwa li o ti sọ ọ.
Isa 58:13-14 Yoruba Bible (YCE)
“Bí ẹ bá dẹ́kun láti máa ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, tí ẹ kò sì máa ṣe ìfẹ́ inú yín lọ́jọ́ mímọ́ mi; bí ẹ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ọjọ́ ìdùnnú, tí ẹ pe ọjọ́ mímọ́ OLUWA ní ọjọ́ ológo; bí ẹ bá yẹ́ ẹ sí, tí ẹ kò yà sí ọ̀nà tiyín, tí ẹ kò máa ṣe ìfẹ́ inú ara yín, tabi kí ẹ máa sọ̀rọ̀ àhesọ; nígbà náà ni inú yín yóo máa dùn láti sin èmi OLUWA, n óo gbe yín gun orí òkè ilẹ̀ ayé, n óo sì mu yín jogún Jakọbu, baba ńlá yín. Èmi OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”
Isa 58:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi, bí ìwọ bá pe ọjọ-ìsinmi ní ohun dídùn àti ọjọ́ mímọ́ OLúWA ní ohun ọ̀wọ̀ àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí kí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí, nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú OLúWA rẹ, èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé, àti láti máa jàdídùn ìní ti Jakọbu baba rẹ.” Ẹnu OLúWA ni ó ti sọ̀rọ̀.