Isa 56:5-6
Isa 56:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Pe, emi o fi ipò kan fun wọn ni ile mi, ati ninu odi mi, ati orukọ ti o dara jù ti awọn ọmọkunrin ati ọmọ-obinrin lọ: emi o fi orukọ ainipẹkun fun wọn, ti a kì yio ke kuro. Ati awọn ọmọ alejò ti nwọn dà ara pọ̀ mọ Oluwa, lati sìn i, ati lati fẹ orukọ Oluwa, lati jẹ iranṣẹ rẹ̀, olukuluku ẹniti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́, ti o si di majẹmu mi mu
Isa 56:5-6 Yoruba Bible (YCE)
n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi, ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ. Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn. “Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín, tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra, tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin
Isa 56:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀ ìrántí kan àti orúkọ kan tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé tí a kì yóò ké kúrò. Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ OLúWA láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ OLúWA àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin