Isa 52:5-8
Isa 52:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ nisisiyi, Oluwa wipe, Kini mo nṣe nihin, ti a kó awọn enia mi lọ lọfẹ? awọn ti o jọba wọn mu nwọn kigbe, li Oluwa wi; titi lojojumọ li a si nsọ̀rọ odì si orukọ mi. Nitorina awọn enia mi yio mọ̀ orukọ mi li ọjọ na: nitori emi li ẹniti nsọrọ: kiyesi i, emi ni. Ẹsẹ ẹniti o mu ihinrere wá ti dara to lori awọn oke, ti nkede alafia; ti nmu ihìn rere ohun rere wá, ti nkede igbala; ti o wi fun Sioni pe, Ọlọrun rẹ̀ njọba! Awọn alóre rẹ yio gbe ohùn soke; nwọn o jumọ fi ohùn kọrin: nitori nwọn o ri li ojukoju, nigbati Oluwa ba mu Sioni pada.
Isa 52:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nisinsinyii, kí ni mo rí yìí? Wọ́n mú àwọn eniyan mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn alákòóso wọn ń pẹ̀gàn, orúkọ mi wá di nǹkan yẹ̀yẹ́? Nítorí náà àwọn eniyan mi yóo mọ orúkọ mi, wọn óo sì mọ̀ ní ọjọ́ náà pé, èmi tí mò ń sọ̀rọ̀, èmi náà nìyí.” Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìyìn rere bọ̀ ti dára tó lórí òkè, ẹni tí ń kéde alaafia, tí ń mú ìyìn rere bọ̀, tí sì ń kéde ìgbàlà, tí ń wí fún Sioni pé, “Ọlọrun rẹ jọba.” Gbọ́, àwọn aṣọ́de rẹ gbóhùn sókè, gbogbo wọn jọ ń kọrin ayọ̀, nítorí wọ́n jọ fi ojú ara wọn rí i, tí OLUWA pada dé sí Sioni.
Isa 52:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni OLúWA wí. “Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,” ni OLúWA wí. “Àti ní ọjọọjọ́ orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo. Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi; nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.” Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìhìnrere ayọ̀ wá, tí wọ́n kéde àlàáfíà, tí ó mú ìhìnrere wá, tí ó kéde ìgbàlà, tí ó sọ fún Sioni pé, “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!” Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀. Nígbà tí OLúWA padà sí Sioni, wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.