Isa 51:1-8

Isa 51:1-8 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ gbọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sáré ìdáǹdè, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá OLUWA, ẹ wo àpáta tí a mú lára rẹ̀, tí a fi gbẹ yín, ati kòtò ibi tí a ti wà yín jáde. Ẹ wo Abrahamu baba yín, ati Sara tí ó bi yín. Òun nìkan ni nígbà tí mo pè é, tí mo súre fún un, tí mo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ eniyan. “OLUWA yóo tu Sioni ninu, yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu; yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA. Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀, pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀. “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin eniyan mi, ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, òfin kan yóo ti ọ̀dọ̀ mi jáde, ìdájọ́ òdodo mi yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan. Ìdáǹdè mi súnmọ́ tòsí, ìgbàlà mi sì ti ń yọ bọ̀. Èmi ni n óo máa ṣe àkóso àwọn eniyan, àwọn erékùṣù yóo gbẹ́kẹ̀lé mi, ìrànlọ́wọ́ mi ni wọn yóo sì máa retí. Ẹ gbójú sókè, ẹ wo ojú ọ̀run, kí ẹ sì wo ayé ní ìsàlẹ̀. Ọ̀run yóo parẹ́ bí èéfín, ayé yóo gbó bí aṣọ, àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ yóo sì kú bíi kòkòrò; ṣugbọn títí lae ni ìgbàlà mi, ìdáǹdè mi kò sì ní lópin. “Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi, ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan; ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà. Ikán yóo jẹ wọ́n bí aṣọ, kòkòrò yóo jẹ wọ́n bí òwú; ṣugbọn ìdáǹdè mi yóo wà títí lae, ìgbàlà mi yóo sì wà láti ìran dé ìran.”

Isa 51:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo àti ẹ̀yin tí ń wá OLúWA: Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde; ẹ wo Abrahamu baba yín, àti Sara, ẹni tó bí i yín. Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni, Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀. Dájúdájú, OLúWA yóò tu Sioni nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni, àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà OLúWA. Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ. “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi; gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi: Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá; ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè. Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan, ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà, àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá sí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn erékùṣù yóò wò mí wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi. Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run, wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀; Àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín, ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin. Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé, òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé. “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́, ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà. Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ; Ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé, àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”