Isa 51:1-23

Isa 51:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

GBỌ ti emi, ẹnyin ti ntẹle ododo, ẹnyin ti nwá Oluwa; wò apáta nì ninu eyiti a ti gbẹ́ nyin, ati ihò kòto nì nibiti a gbe ti wà nyin. Ẹ wò Abrahamu baba nyin, ati Sara ti o bi nyin; nitori on nikan ni mo pè, mo si sure fun u, mo si mu u pọ̀ si i. Nitori Oluwa yio tù Sioni ninu; yio tú gbogbo ibi ofo rẹ̀ ninu; yio si ṣe aginju rẹ̀ bi Edeni, ati aṣálẹ rẹ̀ bi ọgbà Oluwa, ayọ̀ ati inudidùn li a o ri ninu rẹ̀, idupẹ, ati ohùn orin. Tẹtilelẹ si mi, ẹnyin enia mi; si fi eti si mi, iwọ orilẹ-ède mi: nitori ofin kan yio ti ọdọ mi jade lọ, emi o si gbe idajọ mi kalẹ fun imọlẹ awọn enia. Ododo mi wà nitosí; igbala mi ti jade lọ, apá mi yio si ṣe idajọ awọn enia; awọn erekùṣu yio duro dè mi, apá mi ni nwọn o si gbẹkẹle. Ẹ gbé ojú nyin soke si awọn ọrun, ki ẹ si wò aiye nisalẹ: nitori awọn ọrun yio fẹ́ lọ bi ẹ̃fin, aiye o si di ogbó bi ẹwù, awọn ti ngbe inu rẹ̀ yio si kú bakanna: ṣugbọn igbala mi o wà titi lai, ododo mi kì yio si parẹ́. Gbọ́ ti emi, ẹnyin ti o mọ̀ ododo, enia ninu aiya ẹniti ofin mi mbẹ; ẹ máṣe bẹ̀ru ẹgàn awọn enia, ẹ má si ṣe foyà ẹsín wọn. Nitori kòkoro yio jẹ wọn bi ẹ̀wu, idin yio si jẹ wọn bi irun agutan: ṣugbọn ododo mi yio wà titi lai, ati igbala mi lati iran de iran. Ji, ji, gbe agbara wọ̀, Iwọ apa Oluwa; ji, bi li ọjọ igbãni, ni iran atijọ. Iwọ kọ́ ha ke Rahabu, ti o si ṣá Dragoni li ọgbẹ́? Iwọ kọ́ ha gbẹ okun, omi ibu nla wọnni? ti o ti sọ ibú okun di ọ̀na fun awọn ẹni ìrapada lati gbà kọja? Nitorina awọn ẹni-ìrapada Oluwa yio pada, nwọn o si wá si Sioni ti awọn ti orin; ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri inudidùn ati ayọ̀ gbà; ikãnu ati ọ̀fọ yio fò lọ. Emi, ani emi ni ẹniti ntù nyin ninu: tani iwọ, ti iwọ o fi bẹ̀ru enia ti yio kú, ati ọmọ enia ti a ṣe bi koriko. Ti iwọ si gbagbe Oluwa Elẹda rẹ ti o ti nà awọn ọrun, ti o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; ti iwọ si ti mbẹ̀ru nigbagbogbo lojojumọ nitori irúnu aninilara nì, bi ẹnipe o ti mura lati panirun? nibo ni irúnu aninilara na ha gbe wà? Ondè ti a ti ṣí nipo yara ki a ba le tú u silẹ, ati ki o má ba kú sinu ihò, tabi ki onjẹ rẹ̀ má ba tán. Ṣugbọn emi Oluwa Ọlọrun rẹ ti o pin okun ni iyà, eyi ti ìgbi rẹ̀ nhó; Oluwa awọn ọmọ-ogun ni orukọ rẹ̀. Emi si ti fi ọ̀rọ mi si ẹnu rẹ, mo si ti bò ọ mọlẹ ni ojiji ọwọ́ mi, ki emi ki o le gbìn awọn ọrun, ki emi si le fi ipilẹ aiye sọlẹ, ati ki emi le wi fun Sioni pe, Iwọ ni enia mi. Ji, ji, dide duro, iwọ Jerusalemu, ti o ti mu li ọwọ́ Oluwa ago irúnu rẹ̀; iwọ ti mu gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago ìwarìri, iwọ si fọ́n wọn jade. Kò si ẹnikan ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti o bí lati tọ́ ọ; bẹ̃ni kò si ẹniti o fà a lọwọ, ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti on tọ́ dàgba. Ohun meji wọnyi li o débá ọ: tani o kãnu fun ọ? idahoro, on iparun, ati ìyan, on idà: nipa tani emi o tù ọ ninu? Awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti dáku, nwọn dubulẹ ni gbogbo ikorita, bi ẹfọ̀n ninu àwọn: nwọn kún fun ìrúnu Oluwa, ibawi Ọlọrun rẹ. Nitorina gbọ́ eyi na, iwọ ẹniti a pọ́n loju, ti o si mu amuyo, ṣugbọn kì iṣe nipa ọti-waini: Bayi ni Oluwa rẹ Jehofa wi, ati Ọlọrun rẹ ti ngbèja enia rẹ̀, Kiyesi i, emi ti gbà ago ìwárìri kuro lọwọ rẹ, gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago irúnu mi; iwọ kì yio si mu u mọ. Ṣugbọn emi o fi i si ọwọ́ awọn ti o pọ́n ọ loju; ti nwọn ti wi fun ọkàn rẹ pe, Wólẹ, ki a ba le rekọja: iwọ si ti tẹ́ ara rẹ silẹ bi ilẹ, ati bi ita, fun awọn ti o rekọja.

Isa 51:1-23 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ gbọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sáré ìdáǹdè, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá OLUWA, ẹ wo àpáta tí a mú lára rẹ̀, tí a fi gbẹ yín, ati kòtò ibi tí a ti wà yín jáde. Ẹ wo Abrahamu baba yín, ati Sara tí ó bi yín. Òun nìkan ni nígbà tí mo pè é, tí mo súre fún un, tí mo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ eniyan. “OLUWA yóo tu Sioni ninu, yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu; yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA. Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀, pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀. “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin eniyan mi, ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, òfin kan yóo ti ọ̀dọ̀ mi jáde, ìdájọ́ òdodo mi yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan. Ìdáǹdè mi súnmọ́ tòsí, ìgbàlà mi sì ti ń yọ bọ̀. Èmi ni n óo máa ṣe àkóso àwọn eniyan, àwọn erékùṣù yóo gbẹ́kẹ̀lé mi, ìrànlọ́wọ́ mi ni wọn yóo sì máa retí. Ẹ gbójú sókè, ẹ wo ojú ọ̀run, kí ẹ sì wo ayé ní ìsàlẹ̀. Ọ̀run yóo parẹ́ bí èéfín, ayé yóo gbó bí aṣọ, àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ yóo sì kú bíi kòkòrò; ṣugbọn títí lae ni ìgbàlà mi, ìdáǹdè mi kò sì ní lópin. “Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi, ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan; ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà. Ikán yóo jẹ wọ́n bí aṣọ, kòkòrò yóo jẹ wọ́n bí òwú; ṣugbọn ìdáǹdè mi yóo wà títí lae, ìgbàlà mi yóo sì wà láti ìran dé ìran.” Jí, jí! Dìde, OLUWA, jí pẹlu agbára; jí bí ìgbà àtijọ́, bí o ti ṣe sí ìran wa látijọ́. Ṣebí ìwọ ni o gé Rahabu wẹ́lẹwẹ̀lẹ, tí o fi idà gún diragoni? Àbí ìwọ kọ́ ni o mú kí omi òkun gbẹ, omi inú ọ̀gbun ńlá; tí o sọ ilẹ̀ òkun di ọ̀nà, kí àwọn tí o rà pada lè kọjá? Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá, pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni. Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí, wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn; ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ. “Èmi fúnra mi ni mò ń tù ọ́ ninu, ta ni ọ́, tí o fi ń bẹ̀rù eniyan tí yóo kú? Ìwọ ń bẹ̀rù ọmọ eniyan tí a dá, bíi koríko. O gbàgbé OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ, tí ó ta ojú ọ̀run bí aṣọ, tí ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. O wá ń fi gbogbo ọjọ́ ayé bẹ̀rù ibinu àwọn aninilára, nítorí wọ́n múra tán láti pa ọ́ run? Ibinu àwọn aninilára kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́. Láìpẹ́, a óo tú àwọn tí a tẹ̀ lórí ba sílẹ̀. Wọn kò ní kú, wọn kò ní wọ inú isà òkú, wọn kò sì ní wá oúnjẹ tì. “Nítorí èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ, ẹni tí ó rú òkun sókè, tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo; OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ mi. Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu, mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi. Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀, tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ” Jí, jí! Dìde, ìwọ Jerusalẹmu. Ìwọ tí o ti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibinu OLUWA, ìwọ tí OLUWA ti fi ibinu jẹ níyà, tí ojú rẹ wá ń pòòyì. Kò sí ẹni tí yóo tọ́ ọ sọ́nà, ninu gbogbo àwọn ọmọ tí o ti bí, kò sí ẹni tí yóo fà ọ́ lọ́wọ́, ninu gbogbo ọmọ tí o tọ́ dàgbà. Àjálù meji ló dé bá ọ, ta ni yóo tù ọ́ ninu: Ìsọdahoro ati ìparun, ìyàn ati ogun, ta ni yóo tù ọ́ ninu? Àárẹ̀ mú àwọn ọmọ rẹ, wọ́n sùn káàkiri ní gbogbo òpópó, bí ìgalà tí ó bọ́ sinu àwọ̀n. Ibinu OLUWA rọ̀jò lé wọn lórí, àní ìbáwí Ọlọrun rẹ. Nítorí náà, ẹ̀yin tí à ń fi ìyà jẹ, ẹ gbọ́ èyí; ẹ̀yin tí ẹ ti yó láì tíì mu ọtí, Oluwa rẹ, àní OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní, “Wò ó! Mo ti gba ife àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lọ́wọ́ rẹ, O kò ní rí ibinu mi mọ́. Àwọn tí ń dá ọ lóró ni yóo rí ibinu mi, àwọn tí ó wí fún ọ pé, ‘Bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí á gba orí rẹ kọjá;’ tí wọ́n sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀ẹ́lẹ̀, tí wọ́n sọ ọ́ di ojú ọ̀nà wọn, tí wọn óo máa gbà kọjá.”

Isa 51:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo àti ẹ̀yin tí ń wá OLúWA: Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde; ẹ wo Abrahamu baba yín, àti Sara, ẹni tó bí i yín. Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni, Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀. Dájúdájú, OLúWA yóò tu Sioni nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni, àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà OLúWA. Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ. “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi; gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi: Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá; ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè. Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan, ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà, àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá sí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn erékùṣù yóò wò mí wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi. Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run, wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀; Àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín, ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin. Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé, òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé. “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́, ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà. Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ; Ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé, àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.” Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára Ìwọ apá OLúWA; dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì, àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́. Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́ tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ? Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí àti àwọn omi inú ọ̀gbun, Tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá? Àwọn ẹni ìràpadà OLúWA yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò. “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú. Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán, tí ìwọ sì gbàgbé OLúWA ẹlẹ́dàá rẹ, ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́ nítorí ìbínú àwọn aninilára, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun? Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà? Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ wọn kò ní kú sínú túbú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà. Nítorí Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́ Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀, ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ” OLúWA Jí, jí! Gbéra nílẹ̀ ìwọ Jerusalẹmu, ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ OLúWA ago ìbínú rẹ̀, ìwọ tí o ti fà á mu dé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n. Nínú gbogbo ọmọ tí ó bí kò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ ṣọ́nà nínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́ kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́. Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ— ta ni yóò tù ọ́ nínú? Ìparun àti ìdahoro, ìyàn àti idà ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn? Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú; wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà, gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n. Ìbínú OLúWA ti kún inú wọn fọ́fọ́ àti ìbáwí Ọlọ́run yín. Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì Ohun tí OLúWA Olódùmarè yín wí nìyìí, Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn rẹ̀ mọ́, “Kíyèsi i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ rẹ ago tí ó mú ọ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n; láti inú ago náà, ẹ̀kún ìbínú mi, ni ìwọ kì yóò mu mọ́. Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nilójú rẹ lọ́wọ́, àwọn tí ó wí fún ọ pé, ‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lórí rẹ.’ Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lórí i rẹ̀.”