Isa 50:7-9
Isa 50:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ: nitorina emi kì yio dãmu; nitorina ni mo ṣe gbe oju mi ró bi okuta lile, emi si mọ̀ pe oju kì yio tì mi. Ẹniti o dá mi lare wà ni tosí, tani o ba mi jà? jẹ ki a duro pọ̀: tani iṣe ẹlẹ́jọ mi? jẹ ki o sunmọ mi. Kiye si i, Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ, tani o dá mi li ẹbi? wò o, gbogbo wọn o di ogbó bi ẹwù; kokòro yio jẹ wọn run.
Isa 50:7-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́, nítorí náà ojú kò tì mí; nítorí náà mo múra gírí, mo jẹ́ kí ojú mi le koko, mo sì mọ̀ pé ojú kò ní tì mí. Ẹni tí yóo dá mi láre wà nítòsí, ta ló fẹ́ bá mi jà? Ta ló fẹ́ fi ẹ̀sùn kàn mí? Kí olúwarẹ̀ súnmọ́ tòsí mi, kí á jọ kojú ara wa? Wò ó! OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́, ta ni yóo dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn ni yóo gbọ̀n dànù bí aṣọ, kòkòrò yóo sì jẹ wọ́n.
Isa 50:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nítorí OLúWA Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́, a kì yóò dójútì mí. Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí. Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí. Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí? Jẹ́ kí a kojú ara wa! Ta ni olùfisùn mi? Jẹ́ kí ó kò mí lójú! OLúWA Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ; kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.