Isa 50:10-11
Isa 50:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tani ninu nyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ti o gba ohùn iranṣẹ rẹ̀ gbọ́, ti nrìn ninu okùnkun, ti kò si ni imọlẹ? jẹ ki on gbẹkẹ̀le orukọ Oluwa, ki o si fi ẹ̀hìn tì Ọlọrun rẹ̀. Kiye si i, gbogbo ẹnyin ti o dá iná, ti ẹ fi ẹta iná yi ara nyin ká: ẹ mã rìn ninu imọlẹ iná nyin, ati ninu ẹta iná ti ẹ ti dá. Eyi ni yio jẹ ti nyin lati ọwọ́ mi wá; ẹnyin o dubulẹ ninu irora.
Isa 50:10-11 Yoruba Bible (YCE)
Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín, tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu, tí ń rìn ninu òkùnkùn, tí kò ní ìmọ́lẹ̀, ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀. Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná, tí ẹ tan iná yí ara yín ká, ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá; ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín. Ẹ óo wà ninu ìrora.
Isa 50:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù OLúWA tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu? Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn tí kò ní ìmọ́lẹ̀, kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLúWA kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín, ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín, àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá. Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá: Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.