Isa 5:1-5
Isa 5:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NISISIYI, emi o kọ orin si olufẹ ọwọ́n mi, orin olùfẹ mi ọwọ́n niti ọ̀gba àjara rẹ̀. Olufẹ ọwọ́n mi ni ọ̀gba àjara lori okè ẹlẹtù loju: O si sọ ọ̀gba yi i ka, o si ṣà okuta kuro ninu rẹ̀, o si gbìn ayànfẹ àjara si inu rẹ̀, o si kọ ile iṣọ sãrin rẹ̀, o si ṣe ifunti sinu rẹ̀ pẹlu: o si wò pe ki o so eso, ṣugbọn eso kikan li o so. Njẹ nisisiyi, ẹnyin ara Jerusalemu ati ẹnyin ọkunrin Juda, emi bẹ̀ nyin, ṣe idajọ lãrin mi, ati lãrin ọ̀gba àjara mi. Kini a ba ṣe si ọ̀gba àjara mi ti emi kò ti ṣe ninu rẹ̀, nigbati mo wò pe iba so eso, ẽṣe ti o fi so eso kikan? Njẹ nisisiyi, ẹ wá na, emi o sọ ohun ti emi o ṣe si ọ̀gba àjara mi fun nyin: emi o mu ọ̀gba rẹ̀ kuro, a o si jẹ ẹ run, emi o wo ogiri rẹ̀ lu ilẹ, a o si tẹ̀ ẹ mọlẹ.
Isa 5:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ jẹ́ kí n kọrin kan fún olùfẹ́ mi, kí n kọrin nípa ọgbà àjàrà rẹ̀. Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan ní orí òkè kan tí ilẹ̀ ibẹ̀ lọ́ràá. Ó kọ́ ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣa gbogbo òkúta ibẹ̀ kúrò. Ó gbin àjàrà dáradára sinu rẹ̀. Ó kọ́ ilé ìṣọ́ gíga sí ààrin rẹ̀, ó sì ṣe ibi tí wọn yóo ti máa fún ọtí sibẹ. Ó ń retí kí àjàrà rẹ̀ so, ṣugbọn èso kíkan ni ó so. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ati ẹ̀yin ará Juda, mo bẹ̀ yín, ẹ wá ṣe ìdájọ́ láàrin èmi ati ọgbà àjàrà mi. Kí ló tún kù tí ó yẹ kí n ṣe sí ọgbà àjàrà mi tí n kò ṣe? Ìgbà tí mo retí kí ó so èso dídùn, kí ló dé tí ó fi so èso kíkan? Nisinsinyii n óo sọ ohun tí n óo ṣe sí ọgbà àjàrà mi fun yín. N óo tú ọgbà tí mo ṣe yí i ká, iná yóo sì jó o. N óo wó odi tí mo mọ yí i ká, wọn yóo sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.
Isa 5:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀; Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú. Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i. Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀ ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára, ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá. “Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu àti ẹ̀yin ènìyàn Juda ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ọgbà àjàrà mi. Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi. Ju èyí tí mo ti ṣe lọ? Nígbà tí mo ń wá èso dáradára, èéṣe tí ó fi so kíkan? Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi: Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò, a ó sì pa á run, Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀ yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.