Isa 5:1-2
Isa 5:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NISISIYI, emi o kọ orin si olufẹ ọwọ́n mi, orin olùfẹ mi ọwọ́n niti ọ̀gba àjara rẹ̀. Olufẹ ọwọ́n mi ni ọ̀gba àjara lori okè ẹlẹtù loju: O si sọ ọ̀gba yi i ka, o si ṣà okuta kuro ninu rẹ̀, o si gbìn ayànfẹ àjara si inu rẹ̀, o si kọ ile iṣọ sãrin rẹ̀, o si ṣe ifunti sinu rẹ̀ pẹlu: o si wò pe ki o so eso, ṣugbọn eso kikan li o so.
Isa 5:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ jẹ́ kí n kọrin kan fún olùfẹ́ mi, kí n kọrin nípa ọgbà àjàrà rẹ̀. Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan ní orí òkè kan tí ilẹ̀ ibẹ̀ lọ́ràá. Ó kọ́ ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣa gbogbo òkúta ibẹ̀ kúrò. Ó gbin àjàrà dáradára sinu rẹ̀. Ó kọ́ ilé ìṣọ́ gíga sí ààrin rẹ̀, ó sì ṣe ibi tí wọn yóo ti máa fún ọtí sibẹ. Ó ń retí kí àjàrà rẹ̀ so, ṣugbọn èso kíkan ni ó so.
Isa 5:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀; Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú. Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i. Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀ ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára, ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.