Isa 49:8-9
Isa 49:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi ni Oluwa wi, Li akoko itẹwọgba emi ti gbọ́ tirẹ, ati li ọjọ igbala, mo si ti ràn ọ lọwọ: emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, lati fi idi aiye mulẹ, lati mu ni jogun ahoro ilẹ nini wọnni. Ki iwọ ki o le wi fun awọn igbekùn pe, Ẹ jade lọ; fun awọn ti o wà ni okùnkun pe, Ẹ fi ara nyin hàn. Nwọn o jẹ̀ li ọ̀na wọnni, pápa ijẹ wọn o si wà ni gbogbo ibi giga.
Isa 49:8-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo dá ọ lóhùn, lọ́jọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́. Mo ti pa ọ́ mọ́, mo sì ti fi ọ́ dá majẹmu pẹlu àwọn aráyé, láti fìdí ilẹ̀ náà múlẹ̀, láti pín ilẹ̀ tí ó ti di ahoro. Kí o máa sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde,’ ati fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn pé, ‘Ẹ farahàn.’ Wọn óo rí ohun jíjẹ ní gbogbo ọ̀nà, gbogbo orí òkè yóo sì jẹ́ ibùjẹ fún wọn.
Isa 49:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ohun tí OLúWA wí nìyìí: “Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro, Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá’ àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’