Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Isa 49:14-16

Isa 49:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn Sioni wipe, Oluwa ti kọ̀ mi silẹ; Oluwa mi si ti gbagbe mi. Obinrin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ. Kiye si i, emi ti kọ ọ si atẹlẹwọ mi: awọn odi rẹ mbẹ niwaju mi nigbagbogbo.

Pín
Kà Isa 49

Isa 49:14-16 Yoruba Bible (YCE)

Sioni ń wí pé, “OLUWA ti kọ̀ mí sílẹ̀, Oluwa mi ti gbàgbé mi.” OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú? Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀? Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé. Èmi kò ní gbàgbé rẹ. Wò ó! Mo ti fi gègé fín orúkọ rẹ sí àtẹ́lẹwọ́ mi, àwọn odi rẹ sì ńbẹ níwájú mi nígbà gbogbo.

Pín
Kà Isa 49

Isa 49:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “OLúWA ti kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa ti gbàgbé è mi.” “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé Èmi kì yóò gbàgbé rẹ! Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.

Pín
Kà Isa 49
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò