Isa 49:1-6
Isa 49:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbọ ti emi, ẹnyin erekùṣu; ki ẹ si fi etí silẹ, ẹnyin enia lati ọ̀na jijìn wá; Oluwa ti pè mi lati inu wá; lati inu iya mi li o ti dá orukọ mi. O si ti ṣe ẹnu mi bi idà mimú; ninu ojìji ọwọ́ rẹ̀ li o ti pa mi mọ, o si sọ mi di ọfà didán; ninu apó rẹ̀ li o ti pa mi mọ́; O si wi fun mi pe, Iwọ ni iranṣẹ mi, Israeli, ninu ẹniti a o yìn mi logo. Nigbana ni mo wi pe, Emi ti ṣiṣẹ́ lasan, emi ti lò agbara mi lofo, ati lasan: nitõtọ idajọ mi mbẹ lọdọ Oluwa, ati iṣẹ mi lọdọ Ọlọrun mi. Ati nisisiyi, li Oluwa wi, ẹni ti o mọ mi lati inu wá lati ṣe iranṣẹ rẹ̀, lati mu Jakobu pada wá sọdọ rẹ̀, lati ṣà Israeli jọ, ki emi le ni ogo loju Oluwa, Ọlọrun mi yio si jẹ́ agbara mi. O si wipe, O ṣe ohun kekere ki iwọ ṣe iranṣẹ mi, lati gbe awọn ẹyà Jakobu dide, ati lati mu awọn ipamọ Israeli pada: emi o si fi ọ ṣe imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le ṣe igbala mi titi de opin aiye.
Isa 49:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ilẹ̀ etí òkun. Ẹ fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè, láti inú oyún ni OLUWA ti pè mí, láti inú ìyá mi wá ni ó ti dárúkọ mi. Ó ṣe ẹnu mi bí idà mímú, ó fi mí pamọ́ sí ibi òjìji ọwọ́ rẹ̀, ó ṣe mí ní ọfà tí ó mú, ó fi mí pamọ́ sinu apó rẹ̀. Ó sọ fún mi pé, “Iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli, àwọn eniyan óo máa yìn mí lógo nítorí rẹ.” Ṣugbọn mo dáhùn pé, “Mo ti ṣiṣẹ́ àṣedànù. Mo ti lo agbára mi ṣòfò, mo ti fi ṣe àṣedànù, sibẹsibẹ ẹ̀tọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ OLUWA.” Ẹ̀san mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọrun mi, yóo san án fún mi. Nisinsinyii, OLUWA, tí ó ṣẹ̀dá mi ninu oyún, kí n lè jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, láti mú Jakọbu pada tọ̀ ọ́ wá, ati láti mú kí Israẹli kórajọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí mo níyì lójú OLUWA, Ọlọrun mi sì ti di agbára mi. OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun, láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ. Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè kí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé.
Isa 49:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù: gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré: kí a tó bí mi OLúWA ti pè mí; láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi. Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n, ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́: ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán, ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀. Ó sọ fún mi pé, “ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe, Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.” Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán; mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo. Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ OLúWA, èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.” Nísinsin yìí OLúWA wí pé ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wá àti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú OLúWA Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi Òun wí pé: “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́. Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí, kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá sí òpin ilẹ̀ ayé.”