Isa 49:1-2
Isa 49:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbọ ti emi, ẹnyin erekùṣu; ki ẹ si fi etí silẹ, ẹnyin enia lati ọ̀na jijìn wá; Oluwa ti pè mi lati inu wá; lati inu iya mi li o ti dá orukọ mi. O si ti ṣe ẹnu mi bi idà mimú; ninu ojìji ọwọ́ rẹ̀ li o ti pa mi mọ, o si sọ mi di ọfà didán; ninu apó rẹ̀ li o ti pa mi mọ́
Isa 49:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ilẹ̀ etí òkun. Ẹ fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè, láti inú oyún ni OLUWA ti pè mí, láti inú ìyá mi wá ni ó ti dárúkọ mi. Ó ṣe ẹnu mi bí idà mímú, ó fi mí pamọ́ sí ibi òjìji ọwọ́ rẹ̀, ó ṣe mí ní ọfà tí ó mú, ó fi mí pamọ́ sinu apó rẹ̀.
Isa 49:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù: gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré: kí a tó bí mi OLúWA ti pè mí; láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi. Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n, ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́: ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán, ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀.