Isa 48:16 - Compare All Versions

Isa 48:16 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ẹ sunmọ ọdọ mi, ẹ gbọ́ eyi; lati ipilẹ̀ṣẹ emi kò sọ̀rọ ni ikọ̀kọ; lati igbati o ti wà, nibẹ ni mo wà; ati nisisiyi Oluwa Jehofa, on Ẹmi rẹ̀, li o ti rán mi.

Isa 48:16 YCE (Yoruba Bible)

Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, n kò sọ̀rọ̀ ní àṣírí, láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe ni mo ti wà níbẹ̀.” Nisinsinyii, OLUWA, Ọlọrun, ati Ẹ̀mí rẹ̀ ti rán mi.

Isa 48:16 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí: “Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀; ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.” Àti ní àkókò yìí, OLúWA Olódùmarè ni ó ti rán mi, pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀.