Isa 48:1-6
Isa 48:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBỌ́ eyi, ẹnyin ile Jakobu, ti a nfi orukọ Israeli pè, ti o si ti inu omi Juda wọnni jade wá, ti o nfi orukọ Oluwa bura, ti o si ndarukọ Ọlọrun Israeli, ṣugbọn ki iṣe li otitọ, tabi li ododo. Nitori nwọn npè ara wọn ni ti ilu mimọ́ nì, nwọn si gbé ara wọn le Ọlọrun Israeli: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀. Emi ti sọ nkan ti iṣãju wọnni lati ipilẹṣẹ; nwọn si ti jade lati ẹnu mi lọ, emi si fi wọn hàn; emi ṣe wọn lojijì, nwọn si ti ṣẹ. Nitori emi mọ̀ pe olori-lile ni iwọ, ọrùn rẹ jẹ iṣan irin, iwaju rẹ si jẹ idẹ. Li atetekọṣe ni mo tilẹ ti sọ fun ọ; ki o to de ni emi ti fihàn ọ: ki iwọ má ba wipe, Oriṣa mi li o ṣe wọn, ati ere mi gbigbẹ́, ati ere mi didà li o ti pa wọn li aṣẹ. Iwọ ti gbọ́, wò gbogbo eyi; ẹnyin kì yio ha sọ ọ? Emi ti fi ohun titun hàn ọ lati igba yi lọ, ani nkan ti o pamọ́, iwọ kò si mọ̀ wọn.
Isa 48:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè, ọmọ bíbí inú Juda, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra, tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli, ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́. Ẹ̀ ń pe ara yín ní ará ìlú mímọ́, ẹ fẹ̀yìn ti Ọlọrun Israẹli, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun. OLUWA ní, “Láti ìgbà àtijọ́ ni mo ti kéde, àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀, èmi ni mo sọ wọ́n jáde, tí mo sì fi wọ́n hàn. Lójijì mo ṣe wọ́n, nǹkan tí mo sọ sì ṣẹ. Nítorí mo mọ̀ pé alágídí ni yín, olóríkunkun sì ni yín pẹlu. Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́: kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín, kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n, àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’ “Ẹ ti fetí ara yín gbọ́, nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀? Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀.
Isa 48:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ OLúWA tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli— OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀: Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́, ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀; Lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ. Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó; àwọn iṣan ọrùn un yín irin ni wọ́n; iwájú yín idẹ ni Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́; kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé, ‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n; àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́sí i.’ Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí?