Isa 46:1-13 - Compare All Versions
Isa 46:1-13 YBCV (Bibeli Mimọ)
BELI tẹriba, Nebo bẹrẹ̀, oriṣa wọn wà lẹhin awọn ẹranko, ati lẹhin ohun-ọ̀sin; a di ẹrù wiwo rù nyin; ẹrù fun awọn ẹranko ti ãrẹ̀ mu. Nwọn bẹ̀rẹ, nwọn jumọ tẹriba; nwọn kò le gbà ẹrù na silẹ, ṣugbọn awọn tikala wọn lọ si igbèkun. Gbọ́ ti emi, iwọ ile Jakobu, ati gbogbo iyoku ile Israeli, ti mo ti gbe lati inu wá, ti mo ti rù lati inu iyá wá. Ani titi de ogbó emi na ni; ani titi de ewú li emi o rù nyin; emi ti ṣe e, emi o si gbe, nitõtọ emi o rù, emi o si gbàla. Tani ẹnyin o fi mi we, ti yio si ba mi dọgba, ti ẹ o si fi mi jọ, ki awa le jẹ ọ̀gba? Nwọn da wura lati inu apò wá, nwọn si fi iwọ̀n wọ̀n fadaka, nwọn bẹ̀ alagbẹdẹ wura, o si fi i ṣe oriṣa: nwọn tẹriba, nwọn si nsìn. Nwọn gbe e le ejika, nwọn rù u, nwọn si fi i sipò rẹ̀; o si duro: ki yio kuro ni ipò rẹ̀; nitõtọ, ẹnikan yio kọ si i, ṣugbọn ki yio dahùn: bẹ̃ni ki yio gbà a kuro ninu wahala rẹ̀. Ẹ ranti eyi, ẹ si fi ara nyin hàn bi ọkunrin: ẹ gbà a si ọkàn, ẹnyin alarekọja. Ẹ ranti nkan iṣaju atijọ: nitori emi li Ọlọrun, ko si si ẹlomiran, emi li Ọlọrun, ko si si ẹniti o dabi emi. Ẹniti nsọ opin lati ipilẹṣẹ wá, ati nkan ti kò ti iṣe lati igbãni wá, wipe, Imọ mi yio duro, emi o si ṣe gbogbo ifẹ mi. Ẹniti npe idì lati ilà-õrun wá: ọkunrin na ti o mu ìmọ mi ṣẹ lati ilẹ jijìn wá: lõtọ, emi ti sọ ọ, emi o si mu u ṣẹ; emi ti pinnu rẹ̀, emi o si ṣe e pẹlu. Gbọ́ ti emi, ẹnyin alagidi ọkàn, ti o jinà si ododo: Emi mu ododo mi sunmọ tosí; ki yio si jina rére, igbala mi ki yio si duro pẹ́: emi o si fi igbala si Sioni fun Israeli ogo mi.
Isa 46:1-13 YCE (Yoruba Bible)
“Oriṣa Bẹli tẹríba, oriṣa Nebo doríkodò. Orí àwọn ẹran ọ̀sìn ati mààlúù ni àwọn oriṣa wọn wà. Àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rù kiri wá di ẹrù, tí àwọn ẹranko tí ó ti rẹ̀ ń rù. Àwọn mejeeji jọ tẹríba, wọ́n jọ doríkodò, wọn ò lè gba àwọn ẹrù wọn kalẹ̀. Àwọn pàápàá yóo lọ sí ìgbèkùn. “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ati gbogbo ará ilé Israẹli tí ó ṣẹ́kù; ẹ̀yin tí mo pọ̀n láti ọjọ́ tí wọ́n ti bi yín, tí mo sì gbé láti inú oyún. Èmi náà ni, títí di ọjọ́ ogbó yín, n óo gbé yín títí tí ẹ óo fi hewú lórí. Èmi ni mo da yín, n óo sì máa tọ́jú yín, n óo máa gbé yín, n óo sì gbà yín là. “Ta ni ẹ óo fi mí wé? Ta ni ẹ óo fi díwọ̀n mi? Ta ni ẹ lè fi wé mi, kí á lè jọ jẹ́ bákan náà? Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò, wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n. Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa. Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín. Wọn á gbé e lé èjìká wọn, wọn á gbé e sípò rẹ̀, á sì dúró kabẹ̀. Kò ní le kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkankan. Bí eniyan bá ké pè é, kò lè gbọ́, kò lè yọ eniyan ninu ìṣòro rẹ̀. “Ẹ ranti èyí, kí ẹ dà á rò, ẹ fi ọkàn rò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀. Ẹ ranti àwọn nǹkan ti àtijọ́, nítorí pé èmi ni Ọlọrun, kò sí Ọlọrun mìíràn mọ́. Èmi ni Ọlọrun, kò sí ẹni tí ó dà bí mi. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn. Láti ìgbà àtijọ́, ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀. Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ, n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’ Mo pe idì láti ìlà oòrùn, mo sì ti pe ẹni tí yóo mú àbá mi ṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè wá. Mo ti sọ̀rọ̀, n óo sì mú un ṣẹ, mo ti ṣe ìpinnu, n óo sì ṣe é. “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin aláìgbọràn, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà sí ìgbàlà. Mo mú ìdáǹdè mi wá sí tòsí, kò jìnnà mọ́, ìgbàlà mi kò ní pẹ́ dé. N óo fi ìgbàlà mi sí Sioni, fún Israẹli, ògo mi.”
Isa 46:1-13 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Beli tẹrí i rẹ̀ ba, Nebo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀; àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù. Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di àjàgà sí wọn lọ́rùn, ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀; wọn kò lè gba ẹrù náà, àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn. “Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu, gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli, ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún, tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ. Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín, Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró. Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ; Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀. “Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba? Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi tí àwa yóò jọ fi ara wé ara? Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn wọ́n sì wọn fàdákà lórí òsùwọ̀n; wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà, wọn sì tẹríba láti sìn ín. Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí. Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà. Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn; òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀. “Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ, fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀. Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́; Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn; Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi. Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá. Mo wí pé, Ète mi yóò dúró, àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí. Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá; láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ. Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ; èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe. Gbọ́ tèmi, ẹ̀yin alágídí ọkàn, ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo. Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí, kò tilẹ̀ jìnnà rárá; àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró. Èmi yóò fún Sioni ní ìgbàlà ògo mi fún Israẹli.