Isa 45:20 - Compare All Versions

Isa 45:20 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ko ara nyin jọ ki ẹ si wá; ẹ jọ sunmọ tosi, ẹnyin ti o salà ninu awọn orilẹ-ède: awọn ti o gbé igi ere gbigbẹ́ wọn kò ni ìmọ, nwọn si gbadura si ọlọrun ti ko le gba ni.

Isa 45:20 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá; ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá. Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri, tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.

Isa 45:20 YCE (Yoruba Bible)

OLUWA ní: “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ wá, ẹ jọ súnmọ́ bí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kù ninu àwọn orílẹ̀-èdè. Aláìlóye ni àwọn tí ń gbẹ́ ère igi lásán kiri, tí wọ́n sì ń gbadura sí oriṣa tí kò lè gbànìyàn là.