Isa 43:3-5 - Compare All Versions
Isa 43:3-5 YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli, Olugbala rẹ: mo fi Egipti ṣe irapada rẹ, mo si fi Etiopia ati Seba fun ọ. Niwọn bi iwọ ti ṣe iyebiye to loju mi, ti iwọ ṣe ọlọla, emi si ti fẹ ọ: nitorina emi o fi enia rọpò rẹ, ati enia dipo ẹmi rẹ. Má bẹ̀ru: nitori emi wà pẹlu rẹ; emi o mu iru-ọmọ rẹ lati ìla-õrun wá, emi o si ṣà ọ jọ lati ìwọ-õrun wá.
Isa 43:3-5 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ; Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ, Kuṣi àti Seba dípò rẹ. Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi, àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ, Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ, àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ. Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
Isa 43:3-5 YCE (Yoruba Bible)
Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ. Mo fi Ijipti, lélẹ̀, láti rà ọ́ pada, mo sì fi Etiopia ati Seba lélẹ̀ mo ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ. Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ, mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ; mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ. Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn, n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn.