Isa 43:11-28

Isa 43:11-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

Emi, ani emi ni Oluwa; ati lẹhin mi, kò si olugbala kan. Emi ti sọ, mo ti gbalà, mo si ti fi hàn, nigbati ko si ajeji ọlọrun kan lãrin nyin: ẹnyin ni iṣe ẹlẹri mi, li Oluwa wi, pe, Emi li Ọlọrun. Lõtọ, ki ọjọ ki o to wà, Emi na ni, ko si si ẹniti o le gbani kuro li ọwọ́ mi: emi o ṣiṣẹ, tani o le yi i pada? Bayi li Oluwa, olurapada nyin, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Nitori nyin ni mo ṣe ranṣẹ si Babiloni, ti mo si jù gbogbo wọn bi isansa, ati awọn ara Kaldea, sisalẹ si awọn ọkọ̀ igbe-ayọ̀ wọn. Emi ni Oluwa, Ẹni-Mimọ́ nyin, ẹlẹda Israeli Ọba nyin. Bayi li Oluwa wi, ẹniti o la ọ̀na ninu okun, ati ipa-ọ̀na ninu alagbara omi; Ẹniti o mu kẹkẹ ati ẹṣin jade, ogun ati agbara; nwọn o jumọ dubulẹ, nwọn kì yio dide: nwọn run, a pa wọn bi owú fitila. Ẹ máṣe ranti nkan ti iṣaju mọ, ati nkan ti atijọ, ẹ máṣe rò wọn. Kiyesi i, emi o ṣe ohun titun kan; nisisiyi ni yio hù jade; ẹnyin ki yio mọ̀ ọ bi? lõtọ, emi o là ọ̀na kan ninu aginju, ati odò li aṣalẹ̀. Awọn ẹran igbẹ yio yìn mi logo, awọn dragoni ati awọn owiwi; nitori emi o funni li omi li aginjù, ati odo ni aṣalẹ̀, lati fi ohun mimu fun awọn enia mi, ayanfẹ mi; Awọn enia yi ni mo ti mọ fun ara mi; nwọn o fi iyìn mi hàn. Ṣugbọn iwọ kò ké pe mi, Jakobu; ṣugbọn ãrẹ̀ mu ọ nitori mi, iwọ Israeli. Iwọ ko mu ọmọ-ẹran ẹbọ sisun rẹ fun mi wá; bẹ̃ni iwọ ko fi ẹbọ rẹ bu ọlá fun mi. Emi ko fi ọrẹ mu ọ sìn, emi ko si fi turari da ọ li agara. Iwọ ko fi owo rà kalamu olõrun didun fun mi, bẹ̃ni iwọ ko fi ọra ẹbọ rẹ yó mi; ṣugbọn iwọ fi ẹ̀ṣẹ rẹ mu mi ṣe lãla, iwọ si fi aiṣedẽde rẹ da mi li agara. Emi, ani emi li ẹniti o pa irekọja rẹ rẹ́ nitori ti emi tikalami, emi ki yio si ranti ẹ̀ṣẹ rẹ. Rán mi leti: ki a jumọ sọ ọ; iwọ rò, ki a le da ọ lare. Baba rẹ iṣãju ti ṣẹ̀, awọn olukọni rẹ ti yapa kuro lọdọ mi. Nitorina mo ti sọ awọn olori ibi mimọ́ na di aimọ́, mo si ti fi Jakobu fun egún, ati Israeli fun ẹ̀gan.

Isa 43:11-28 Yoruba Bible (YCE)

“Èmi ni OLUWA, kò sí olùgbàlà kan, yàtọ̀ sí mi. Mo ti sọ̀rọ̀ ìṣípayá, mo ti gba eniyan là, mo sì ti kéde, nígbà tí kò sí Ọlọrun àjèjì láàrin yín; ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Èmi ni Ọlọrun, láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi ni. Kò sí ẹnìkan tí ó lè gba eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ mi: Ta ni le dínà ohun tí mo bá níí ṣe?” OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní, “N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín, n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè, ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún. Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín, Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.” OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun, tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá; ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun; wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́, wọ́n kú bí iná fìtílà. ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́, kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá. Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titun ó ti yọ jáde nisinsinyii, àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀? N óo la ọ̀nà ninu aginjù, n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀. Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo, ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò; nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀, kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu: Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi, kí wọ́n lè kéde ògo mi. “Sibẹsibẹ, ẹ kò ké pè mí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ọ̀rọ̀ mi ti su yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ẹ kò wá fi aguntan rúbọ sí mi, tabi kí ẹ wá fi ẹbọ rírú bu ọlá fún mi. N kò fi tipátipá mu yín rúbọ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sọ pé dandan ni kí ẹ mú turari wá. Ẹ kò fowó yín ra turari olóòórùn dídùn fún mi, tabi kí ẹ fi ọ̀rá ẹbọ yín tẹ́ mi lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ yín yọ mí lẹ́nu, ẹ sì ń dààmú mi pẹlu àìdára yín. Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, nítorí ti ara mi; n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́. “Ẹ rán mi létí ọ̀rọ̀ yín kí á jọ ṣàríyànjiyàn; ẹ ro ẹjọ́ tiyín, kí á lè da yín láre. Baba ńlá yín àkọ́kọ́ ṣẹ̀, àwọn aṣiwaju yín náà sì ṣẹ̀ mí. Nítorí náà mo sọ àwọn olórí ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, mo fi Jakọbu sílẹ̀ fún ìparun; mo sì sọ Israẹli di ẹni ẹ̀sín.”

Isa 43:11-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èmi, àní Èmi, Èmi ni OLúWA, yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn. Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLúWA wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?” Èyí ni ohun tí OLúWA wí olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli; “Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeli láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, gbogbo ará Babeli nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga. Èmi ni OLúWA, Ẹni Mímọ́ rẹ, Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.” Èyí ni ohun tí OLúWA wí Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun, ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi, ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde, àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀, wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́, wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà: “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá; má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́. Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun! Nísinsin yìí ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí? Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá. Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi, àwọn ajáko àti àwọn òwìwí, nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ sísá, láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi, àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi. “Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí, ìwọ Jakọbu, àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi ìwọ Israẹli. Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun, tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ. Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí. Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi, tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí. Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín. “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi, tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́. Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi, jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀; ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn. Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀; àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún àti Israẹli fún ẹ̀gàn.