Isa 43:1-13
Isa 43:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN nisisiyi bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, Jakobu, ati ẹniti o mọ ọ, Israeli, Má bẹru: nitori mo ti rà ọ pada, mo ti pè ọ li orukọ rẹ, ti emi ni iwọ. Nigbati iwọ ba nlà omi kọja, emi o pẹlu rẹ; ati lãrin odò, nwọn ki yio bò ọ mọlẹ: nigbati iwọ ba nrìn ninu iná, ki yio jo ọ, bẹ̃ni ọwọ́-iná ki yio ràn ọ. Nitori emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli, Olugbala rẹ: mo fi Egipti ṣe irapada rẹ, mo si fi Etiopia ati Seba fun ọ. Niwọn bi iwọ ti ṣe iyebiye to loju mi, ti iwọ ṣe ọlọla, emi si ti fẹ ọ: nitorina emi o fi enia rọpò rẹ, ati enia dipo ẹmi rẹ. Má bẹ̀ru: nitori emi wà pẹlu rẹ; emi o mu iru-ọmọ rẹ lati ìla-õrun wá, emi o si ṣà ọ jọ lati ìwọ-õrun wá. Emi o wi fun ariwa pe, Da silẹ; ati fun gusu pe, Máṣe da duro; mu awọn ọmọ mi ọkunrin lati okere wá, ati awọn ọmọ mi obinrin lati opin ilẹ wá. Olukuluku ẹniti a npè li orukọ mi: nitori mo ti dá a fun ogo mi, mo ti mọ ọ, ani, mo ti ṣe e pé. Mu awọn afọju enia ti o li oju jade wá, ati awọn aditi ti o li eti. Jẹ ki gbogbo awọn orilẹ-ède ṣa ara wọn jọ pọ̀, ki awọn enia pejọ; tani ninu wọn ti o le sọ eyi, ti o si le fi ohun atijọ han ni? jẹ ki wọn mu awọn ẹlẹri wọn jade, ki a le dá wọn lare; nwọn o si gbọ́, nwọn o si wipe, Õtọ ni. Ẹnyin li ẹlẹri mi, ni Oluwa wi, ati iranṣẹ mi ti mo ti yàn: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki ẹ si gbà mi gbọ́ ki o si ye nyin pe, Emi ni; a kò mọ̀ Ọlọrun kan ṣãju mi, bẹ̃ni ọkan kì yio si hù lẹhin mi. Emi, ani emi ni Oluwa; ati lẹhin mi, kò si olugbala kan. Emi ti sọ, mo ti gbalà, mo si ti fi hàn, nigbati ko si ajeji ọlọrun kan lãrin nyin: ẹnyin ni iṣe ẹlẹri mi, li Oluwa wi, pe, Emi li Ọlọrun. Lõtọ, ki ọjọ ki o to wà, Emi na ni, ko si si ẹniti o le gbani kuro li ọwọ́ mi: emi o ṣiṣẹ, tani o le yi i pada?
Isa 43:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu, gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí, Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ. Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada; mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́. Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá, n óo wà pẹlu rẹ; nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá, kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀, nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ. Ahọ́n iná kò ní jó ọ run. Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ. Mo fi Ijipti, lélẹ̀, láti rà ọ́ pada, mo sì fi Etiopia ati Seba lélẹ̀ mo ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ. Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ, mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ; mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ. Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn, n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn. N óo pàṣẹ fún ìhà àríwá pé, ‘Dá wọn sílẹ̀.’ N óo sọ fún ìhà gúsù pé, ‘O kò gbọdọ̀ dá wọn dúró.’ Kó àwọn ọmọ mi ọkunrin wá láti òkèèrè, sì kó àwọn ọmọ mi obinrin wá láti òpin ayé, gbogbo àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè, àwọn tí mo dá fún ògo mi, àwọn tí mo fi ọwọ́ mi ṣẹ̀dá wọn.” Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde, àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́, wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di. Jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè péjọ, kí àwọn eniyan àgbáyé parapọ̀. Èwo ninu wọn ni ó lè kéde irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó lè fi àwọn ohun àtijọ́ hàn wá; kí wọn pe ẹlẹ́rìí wọn wá, kí á lè mọ̀ pé ẹjọ́ wọn tọ́, kí àwọn ẹlòmíràn lè gbọ́, kì wọn sì jẹ́rìí pé, “Òtítọ́ ni.” OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn; kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́, kí ó sì ye yín pé, Èmi ni. A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi, òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi. “Èmi ni OLUWA, kò sí olùgbàlà kan, yàtọ̀ sí mi. Mo ti sọ̀rọ̀ ìṣípayá, mo ti gba eniyan là, mo sì ti kéde, nígbà tí kò sí Ọlọrun àjèjì láàrin yín; ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Èmi ni Ọlọrun, láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi ni. Kò sí ẹnìkan tí ó lè gba eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ mi: Ta ni le dínà ohun tí mo bá níí ṣe?”
Isa 43:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí OLúWA wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Israẹli: “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè; Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe. Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ; àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá, kò ní jó ọ; ahọ́n iná kò ní jó ọ lára. Nítorí Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ; Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ, Kuṣi àti Seba dípò rẹ. Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi, àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ, Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ, àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ. Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn. Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’ Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’ Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé— ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́, tí mo dá fún ògo mi, tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.” Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde, tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití. Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọ àwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀. Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀? Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá láti fihàn pé wọ́n tọ̀nà tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.” “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLúWA wí, “Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́ tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà. Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá, tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi. Èmi, àní Èmi, Èmi ni OLúWA, yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn. Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLúWA wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”