Isa 42:17-25

Isa 42:17-25 Yoruba Bible (YCE)

A óo ká àwọn tí ó gbójú lé ère lọ́wọ́ kò, ojú yóo sì tì wọ́n patapata àwọn tí ń wí fún ère gbígbẹ́ pé: ‘Ẹ̀yin ni Ọlọrun wa.’ ” OLUWA ní: “Gbọ́, ìwọ adití, sì wò ó, ìwọ afọ́jú, kí o lè ríran. Ta ni afọ́jú, bíkòṣe iranṣẹ mi? Ta sì ni adití, bíkòṣe ẹni tí mo rán níṣẹ́? Ta ni ó fọ́jú tó ẹni tí mo yà sọ́tọ̀, tabi ta ni ojú rẹ̀ fọ́ tó ti iranṣẹ OLUWA? Ó ń wo ọpọlọpọ nǹkan, ṣugbọn kò ṣe akiyesi wọn. Etí rẹ̀ là sílẹ̀, ṣugbọn kò gbọ́ràn.” Ó wu OLUWA láti gbé òfin rẹ̀ ga ati láti ṣe é lógo nítorí òdodo rẹ̀. Ṣugbọn a ti ja àwọn eniyan wọnyi lólè, a sì ti kó wọn lẹ́rù, a ti sé gbogbo wọn mọ́ inú ihò ilẹ̀, a sì ti fi wọ́n pamọ́ sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. A fogun kó wọn, láìsí ẹni tí yóo gbà wọ́n sílẹ̀, a kó wọn lẹ́rú, láìsí ẹnikẹ́ni tí yóo sọ pé: “Ẹ dá wọn pada.” Èwo ninu yín ló fetí sí èyí, tabi tí yóo farabalẹ̀ gbọ́ nítorí ẹ̀yìn ọ̀la? Ta ló fa Jakọbu lé akónilẹ́rù lọ́wọ́, ta ló sì fa Israẹli lé àwọn ọlọ́ṣà lọ́wọ́? Ṣebí OLUWA tí a ti ṣẹ̀ ni, ẹni tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀; tí wọn kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́. Nítorí náà ó jẹ́ kí wọ́n rí ibinu òun, ó sì fi agbára ogun rẹ̀ hàn wọ́n. Ó tanná ràn án lọ́tùn-ún lósì, sibẹ kò yé e; iná jó o, sibẹsibẹ kò fi ṣe àríkọ́gbọ́n.

Isa 42:17-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà, tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú. “Gbọ́, ìwọ adití, wò ó, ìwọ afọ́jú, o sì rí! Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi, àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán? Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí, ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ OLúWA? Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí; etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkan kan.” Ó dùn mọ́ OLúWA nítorí òdodo rẹ̀ láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun tí a sì kó lẹ́rú, gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun, tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n. Wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀; wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.” Ta ni nínú yín tí yóò tẹ́tí sí èyí tàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀? Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun, àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí? Kì í ha ṣe OLúWA ni, ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí? Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀; wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ. Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí, rògbòdìyàn ogun. Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀ èdè kò yé wọn; ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.