Isa 41:17-20
Isa 41:17-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati talakà ati alaini nwá omi, ti kò si si, ti ahọn wọn si gbẹ fun ongbẹ, emi Oluwa yio gbọ́ ti wọn, emi Ọlọrun Israeli ki yio kọ̀ wọn silẹ. Emi o ṣi odò nibi giga, ati orisún lãrin afonifoji: emi o sọ aginjù di abàta omi, ati ilẹ gbigbẹ di orisun omi. Emi o fi igi kedari si aginjù, ati igi ṣita, ati mirtili, ati igi oróro; emi o gbìn igi firi ati igi pine ati igi boksi pọ̀ ni aginjù. Ki nwọn ki o le ri, ki nwọn ki o si mọ̀, ki nwọn si gbèro, ki o si le yé won pọ̀, pe, ọwọ́ Oluwa li o ti ṣe eyi, ati pe Ẹni-Mimọ Israeli ni o ti dá a.
Isa 41:17-20 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí, tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ, èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn, èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀. N óo ṣí odò lórí àwọn òkè, ati orísun láàrin àwọn àfonífojì; n óo sọ aṣálẹ̀ di adágún odò, ilẹ̀ gbígbẹ yóo sì di orísun omi. N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀, pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi. N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀, n óo gbin igi firi ati pine papọ̀. Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀, kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀, pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.”
Isa 41:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Àwọn tálákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí; ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n Èmi OLúWA yóò dá wọn lóhùn; Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga àti orísun omi ní àárín Àfonífojì. Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi, àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi. Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀ igi kedari àti kasia, maritili àti olifi. Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù, igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀, kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn, pé ọwọ́ OLúWA ni ó ti ṣe èyí, àti pé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.