Isa 41:13-20

Isa 41:13-20 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ, ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, èmi ni mo sọ fún ọ pé kí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.” Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín. Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun, tí ó mú, tí ó sì ní eyín, ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú; ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù. Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ, ìjì yóo sì fọ́n wọn ká. Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWA ẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli. “Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí, tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ, èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn, èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀. N óo ṣí odò lórí àwọn òkè, ati orísun láàrin àwọn àfonífojì; n óo sọ aṣálẹ̀ di adágún odò, ilẹ̀ gbígbẹ yóo sì di orísun omi. N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀, pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi. N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀, n óo gbin igi firi ati pine papọ̀. Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀, kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀, pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.”

Isa 41:13-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù; Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni OLúWA wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun, tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá, ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú, a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò. Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú, àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú OLúWA ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. “Àwọn tálákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí; ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n Èmi OLúWA yóò dá wọn lóhùn; Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga àti orísun omi ní àárín Àfonífojì. Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi, àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi. Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀ igi kedari àti kasia, maritili àti olifi. Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù, igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀, kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn, pé ọwọ́ OLúWA ni ó ti ṣe èyí, àti pé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.

Isa 41:13-20

Isa 41:13-20 YBCVIsa 41:13-20 YBCVIsa 41:13-20 YBCV