Isa 41:13-14
Isa 41:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori emi Oluwa Ọlọrun rẹ yio di ọwọ́ ọ̀tun rẹ mu, emi o wi fun ọ pe, Má bẹ̀ru; emi o ràn ọ lọwọ. Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu kòkoro, ati ẹnyin ọkunrin Israeli; emi o ràn ọ lọwọ, bẹ̃ni Oluwa ati Oluràpada rẹ wi, Ẹni-mimọ́ Israeli.
Pín
Kà Isa 41Isa 41:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ, ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, èmi ni mo sọ fún ọ pé kí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.” Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín.
Pín
Kà Isa 41Isa 41:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù; Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni OLúWA wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
Pín
Kà Isa 41