Isa 41:1-29
Isa 41:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAKẸ niwaju mi, Ẹnyin erekùṣu; si jẹ ki awọn enia tún agbara wọn ṣe: jẹ ki wọn sunmọ tosí; nigbana ni ki wọn sọ̀rọ: jẹ ki a jumọ sunmọ tosí fun idajọ. Tali o gbe olododo dide lati ìla-õrun wa, ti o pè e si ẹsẹ rẹ̀, ti o fi awọn orilẹ-ède fun u niwaju rẹ̀, ti o si fi ṣe akoso awọn ọba? o fi wọn fun idà rẹ̀ bi ekuru, ati bi akekù iyàngbo fun ọrun rẹ̀. O lepa wọn, o si kọja li alafia; nipa ọ̀na ti kò ti fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ ri. Tali o ti dá a ti o si ti ṣe e, ti o npè awọn iran lati ipilẹṣẹ̀ wá? Emi Oluwa ni; ẹni-ikini, ati pẹlu ẹni-ikẹhìn; Emi na ni. Awọn erekùṣu ri i, nwọn si bẹ̀ru; aiya nfò awọn opin aiye; nwọn sunmọ tosí, nwọn si wá. Olukulùku ràn aladugbo rẹ̀ lọwọ; o si wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ mu ara le. Bẹ̃ni gbẹnàgbẹnà ngbà alagbẹdẹ wura niyànju, ati ẹniti nfi ọmọ-owú dán a, ngbà ẹniti nlù ògún niyànju; wipe, o ṣetan fun mimọlù: o si fi iṣo kàn a mọra ki o má le ṣi. Ṣugbọn iwọ, Israeli, ni iranṣẹ mi, Jakobu ẹniti mo ti yàn, iru-ọmọ Abrahamu ọrẹ mi. Ẹniti mo ti mu lati opin aiye wá, ti mo ti pè ọ lati ọdọ awọn olori enia ibẹ, ti mo si wi fun ọ pe, Iwọ ni iranṣẹ mi; mo ti yàn ọ, emi kò si ni ta ọ nù, Iwọ má bẹ̀ru; nitori mo wà pẹlu rẹ; má foyà; nitori emi ni Ọlọrun rẹ: emi o fun ọ ni okun; nitõtọ, emi o ràn ọ lọwọ; nitõtọ, emi o fi ọwọ́ ọ̀tun ododo mi gbe ọ sokè. Kiyesi i, gbogbo awọn ti o binu si ọ ni oju o tì, nwọn o si dãmu: nwọn o dabi asan; awọn ti o si mba ọ jà yio ṣegbe. Iwọ o wá wọn, iwọ kì yio si rí wọn, ani awọn ti o ba ọ jà: awọn ti o mba ọ jagun yio dabi asan, ati bi ohun ti kò si. Nitori emi Oluwa Ọlọrun rẹ yio di ọwọ́ ọ̀tun rẹ mu, emi o wi fun ọ pe, Má bẹ̀ru; emi o ràn ọ lọwọ. Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu kòkoro, ati ẹnyin ọkunrin Israeli; emi o ràn ọ lọwọ, bẹ̃ni Oluwa ati Oluràpada rẹ wi, Ẹni-mimọ́ Israeli. Kiyesi i, emi ti ṣe ọ bi ohun-èlo ipakà mimú titun ti o ni ehín; iwọ o tẹ̀ awọn òke-nla, iwọ o si gún wọn kunná, iwọ o si sọ awọn oke kékèké di iyàngbo. Iwọ o fẹ́ wọn, ẹfũfu yio si fẹ́ wọn lọ, ãjà yio si tú wọn ká: iwọ o si yọ̀ ninu Oluwa, iwọ o si ṣogo ninu Ẹni-Mimọ Israeli. Nigbati talakà ati alaini nwá omi, ti kò si si, ti ahọn wọn si gbẹ fun ongbẹ, emi Oluwa yio gbọ́ ti wọn, emi Ọlọrun Israeli ki yio kọ̀ wọn silẹ. Emi o ṣi odò nibi giga, ati orisún lãrin afonifoji: emi o sọ aginjù di abàta omi, ati ilẹ gbigbẹ di orisun omi. Emi o fi igi kedari si aginjù, ati igi ṣita, ati mirtili, ati igi oróro; emi o gbìn igi firi ati igi pine ati igi boksi pọ̀ ni aginjù. Ki nwọn ki o le ri, ki nwọn ki o si mọ̀, ki nwọn si gbèro, ki o si le yé won pọ̀, pe, ọwọ́ Oluwa li o ti ṣe eyi, ati pe Ẹni-Mimọ Israeli ni o ti dá a. Mú ẹjọ nyin wá, ni Oluwa wi; mú ọràn dajudaju nyin jade wá, ni ọba Jakobu wi. Jẹ ki wọn mú wọn jade wá, ki wọn si fi ohun ti yio ṣe hàn ni: jẹ ki wọn fi ohun iṣãju hàn, bi nwọn ti jẹ, ki awa ki o lè rò wọn, ki a si mọ̀ igbẹ̀hin wọn; tabi ki nwọn sọ ohun wọnni ti mbọ̀ fun wa. Fi ohun ti mbọ̀ lẹhìn eyi hàn, ki awa ki o le mọ̀ pe ọlọrun ni nyin: nitõtọ, ẹ ṣe rere, tabi ẹ ṣe buburu, ki ẹ̀ru le bà wa, ki a le jumọ ri i. Kiyesi i, lati nkan asan ni nyin, iṣẹ nyin si jẹ asan: irira ni ẹniti o yàn nyin. Emi ti gbé ẹnikan dide lati ariwa, on o si wá: lati ilà-õrun ni yio ti ké pe orukọ mi: yio si wá sori awọn ọmọ-alade bi sori àmọ, ati bi alamọ̀ ti itẹ̀ erupẹ. Tani o ti fi hàn lati ipilẹ̀ṣẹ, ki awa ki o le mọ̀? ati nigba iṣãju, ki a le wi pe, Olododo ni on? nitõtọ, kò si ẹnikan ti o fi hàn, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o sọ ọ, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o gbọ́ ọ̀rọ nyin. Ẹni-ikini o wi fun Sioni pe, Wò o, on na nĩ: emi o fi ẹnikan ti o mú ihinrere wá fun Jerusalemu. Nitori mo wò, kò si si ẹnikan; ani ninu wọn, kò si si olugbimọ̀ kan, nigbati mo bere lọwọ wọn, kò si ẹniti o le dahùn ọ̀rọ kan. Kiyesi i, asan ni gbogbo wọn; asan ni iṣẹ wọn; ẹfũfu ati rudurudu ni ere didà wọn.
Isa 41:1-29 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin erékùṣù, kí àwọn eniyan gba agbára kún agbára wọn, kí wọ́n súnmọ́ ìtòsí, kí wọ́n sọ tẹnu wọn, ẹ jẹ́ kí á pàdé ní ilé ẹjọ́. “Ta ló gbé ẹnìkan dìde ní ìhà ìlà oòrùn? Tí ó ń ṣẹgun ní ibikíbi tí ó bá fẹsẹ̀ tẹ̀? Ta ló fi àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́ tí ó fi lè tẹ àwọn ọba mọ́lẹ̀? Idà rẹ̀ gé wọn bí eruku, ọfà rẹ̀ sì tú wọn ká bí àgékù koríko. A máa lépa wọn, a sì máa kọjá wọn láìléwu, ní ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tẹ̀ rí. Ta ló ṣe èyí? Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni? Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀? Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn. “Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù bà wọ́n, gbogbo òpin ayé gbọ̀n rìrì wọ́n ti súnmọ́ tòsí, wọ́n ti dé. Olukuluku ń ran ẹnìkejì rẹ̀ lọ́wọ́, ó ń sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ṣara gírí.’ Agbẹ́gilére ń gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú ẹni tí ń fi òòlù lu irin ń kí ẹni tí ń dán irin tí wọ́n ti rọ, Ó ń wí pé: ‘Òjé tí a fi jó o dára.’ Wọ́n kàn án ní ìṣó, ó le dáradára, kò le mì. “Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi, Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn, ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi. Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé, tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ, mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́, mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’ Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ. N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́; ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró. “Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ run ni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú. Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán, wọn óo sì ṣègbé. O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì, o kò ní rí wọn. Àwọn tí ó gbógun tì ọ́ yóo di òfo patapata. Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ, ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, èmi ni mo sọ fún ọ pé kí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.” Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín. Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun, tí ó mú, tí ó sì ní eyín, ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú; ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù. Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ, ìjì yóo sì fọ́n wọn ká. Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWA ẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli. “Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí, tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ, èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn, èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀. N óo ṣí odò lórí àwọn òkè, ati orísun láàrin àwọn àfonífojì; n óo sọ aṣálẹ̀ di adágún odò, ilẹ̀ gbígbẹ yóo sì di orísun omi. N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀, pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi. N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀, n óo gbin igi firi ati pine papọ̀. Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀, kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀, pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.” OLUWA, Ọba Jakọbu, ní: “Ẹ̀yin oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ ro ẹjọ́ yín, kí ẹ mú ẹ̀rí tí ó dájú wá lórí ohun tí ẹ bá ní sọ. Ẹ mú wọn wá, kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa; kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa. Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò; kí á lè mọ àyọrísí wọn, tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.” OLUWA ní, “Ẹ sọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la fún wa, kí á lè mọ̀ pé oriṣa ni yín; ẹ ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú kan, kí á rí i, kí ẹ̀rù sì bà wá. Ẹ wò ó! Òfo ni yín, òfo sì ni iṣẹ́ ọwọ́ yín, ẹni ìríra ni ẹni tí ó bá yàn yín. Mo ti gbé ẹnìkan dìde láti ìhà àríwá, ó sì ti dé. Láti ìlà oòrùn ni yóo ti pe orúkọ mi; yóo máa gún àwọn ọba mọ́lẹ̀ bì ìgbà tí wọ́n gún nǹkan ninu odó, àní, bí ìgbà tí amọ̀kòkò bá ń gún amọ̀. Ta ló kéde rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, kí á lè mọ̀, ta ló sọ nípa rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ kí á lè sọ pé, ‘Olóòótọ́ ni?’ Kò sí ẹni tí ó sọ ọ́, kò sí ẹni tí ó kéde rẹ̀; ẹnìkankan kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi OLUWA ni mo ti kọ́kọ́ sọ fún Sioni, tí mo sì ròyìn ayọ̀ náà fún Jerusalẹmu. Nígbà tí mo wo ààrin àwọn wọnyi, kò sí olùdámọ̀ràn kan, tí ó lè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ní ìbéèrè. Wò ó! Ìtànjẹ lásán ni gbogbo wọn, òfo ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn: Ẹ̀fúùfù lásán ni àwọn ère tí wọ́n gbẹ́.”
Isa 41:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú mi ẹ̀yin erékùṣù! Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tún agbára wọn ṣe! Jẹ́ kí wọn wá síwájú kí wọn sọ̀rọ̀: Jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́. “Ta ni ó ti ru ẹnìkan sókè láti ìlà-oòrùn wá, tí ó pè é ní olódodo sí iṣẹ́ tirẹ̀? Ó gbé àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájú rẹ̀. Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀, láti kù ú ní ìyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀. Ó ń lépa wọn ó sì ń kọjá ní àlàáfíà, ní ojú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí. Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé, tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe? Èmi OLúWA pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọn àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.” Àwọn erékùṣù ti rí i wọ́n bẹ̀rù; ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì. Wọ́n súnmọ́ tòsí wọ́n sì wá síwájú Èkínní ran èkejì lọ́wọ́ ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé “Jẹ́ alágbára!” Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú, àti ẹni tí ó fi òòlù dán mú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú. Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, “Ó dára.” Ó fi ìṣó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀. “Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi, Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn, ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi, mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé, láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́. Èmi wí pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;’ Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi. “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà; àwọn tó ń bá ọ jà yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ kì yóò rí wọn. Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́ yóò dàbí ohun tí kò sí. Nítorí Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù; Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni OLúWA wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun, tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá, ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú, a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò. Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú, àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú OLúWA ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. “Àwọn tálákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí; ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n Èmi OLúWA yóò dá wọn lóhùn; Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga àti orísun omi ní àárín Àfonífojì. Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi, àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi. Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀ igi kedari àti kasia, maritili àti olifi. Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù, igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀, kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn, pé ọwọ́ OLúWA ni ó ti ṣe èyí, àti pé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí. “Mú ẹjọ́ wá,” ni OLúWA wí. “Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jakọbu wí “Mú àwọn ère òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún wa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́, kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọn kí àwa sì mọ àbájáde wọn ní ìparí. Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá, ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dání kí àwa kí ó lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín. Ẹ ṣe nǹkan kan, ìbá à ṣe rere tàbí búburú, tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa. Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko jásí nǹkan kan iṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun; ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra. “Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọ ẹnìkan láti ìlà-oòrùn tí ó pe orúkọ mi. Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n, àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀. Ta ni ó sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, tí àwa kò bá fi mọ̀, tàbí ṣáájú àkókò, tí àwa kò bá fi wí pé, ‘Òun sọ òtítọ́’? Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa èyí, ẹnikẹ́ni kò sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Wò ó, àwọn nìyìí!’ Mo fún Jerusalẹmu ní ìránṣẹ́ ìrò ìròyìn ayọ̀ kan. Èmi wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan— kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó lè mú ìmọ̀ràn wá, kò sí ẹnìkan tí ó lè dáhùn nígbà tí mo bi wọ́n. Kíyèsi i, irọ́ ni gbogbo wọn! Gbogbo ìṣe wọn jásí asán; àwọn ère wọn kò ṣé kò yà fún afẹ́fẹ́ àti dàrúdàpọ̀.