Isa 41:1-14

Isa 41:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

DAKẸ niwaju mi, Ẹnyin erekùṣu; si jẹ ki awọn enia tún agbara wọn ṣe: jẹ ki wọn sunmọ tosí; nigbana ni ki wọn sọ̀rọ: jẹ ki a jumọ sunmọ tosí fun idajọ. Tali o gbe olododo dide lati ìla-õrun wa, ti o pè e si ẹsẹ rẹ̀, ti o fi awọn orilẹ-ède fun u niwaju rẹ̀, ti o si fi ṣe akoso awọn ọba? o fi wọn fun idà rẹ̀ bi ekuru, ati bi akekù iyàngbo fun ọrun rẹ̀. O lepa wọn, o si kọja li alafia; nipa ọ̀na ti kò ti fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ ri. Tali o ti dá a ti o si ti ṣe e, ti o npè awọn iran lati ipilẹṣẹ̀ wá? Emi Oluwa ni; ẹni-ikini, ati pẹlu ẹni-ikẹhìn; Emi na ni. Awọn erekùṣu ri i, nwọn si bẹ̀ru; aiya nfò awọn opin aiye; nwọn sunmọ tosí, nwọn si wá. Olukulùku ràn aladugbo rẹ̀ lọwọ; o si wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ mu ara le. Bẹ̃ni gbẹnàgbẹnà ngbà alagbẹdẹ wura niyànju, ati ẹniti nfi ọmọ-owú dán a, ngbà ẹniti nlù ògún niyànju; wipe, o ṣetan fun mimọlù: o si fi iṣo kàn a mọra ki o má le ṣi. Ṣugbọn iwọ, Israeli, ni iranṣẹ mi, Jakobu ẹniti mo ti yàn, iru-ọmọ Abrahamu ọrẹ mi. Ẹniti mo ti mu lati opin aiye wá, ti mo ti pè ọ lati ọdọ awọn olori enia ibẹ, ti mo si wi fun ọ pe, Iwọ ni iranṣẹ mi; mo ti yàn ọ, emi kò si ni ta ọ nù, Iwọ má bẹ̀ru; nitori mo wà pẹlu rẹ; má foyà; nitori emi ni Ọlọrun rẹ: emi o fun ọ ni okun; nitõtọ, emi o ràn ọ lọwọ; nitõtọ, emi o fi ọwọ́ ọ̀tun ododo mi gbe ọ sokè. Kiyesi i, gbogbo awọn ti o binu si ọ ni oju o tì, nwọn o si dãmu: nwọn o dabi asan; awọn ti o si mba ọ jà yio ṣegbe. Iwọ o wá wọn, iwọ kì yio si rí wọn, ani awọn ti o ba ọ jà: awọn ti o mba ọ jagun yio dabi asan, ati bi ohun ti kò si. Nitori emi Oluwa Ọlọrun rẹ yio di ọwọ́ ọ̀tun rẹ mu, emi o wi fun ọ pe, Má bẹ̀ru; emi o ràn ọ lọwọ. Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu kòkoro, ati ẹnyin ọkunrin Israeli; emi o ràn ọ lọwọ, bẹ̃ni Oluwa ati Oluràpada rẹ wi, Ẹni-mimọ́ Israeli.

Isa 41:1-14 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin erékùṣù, kí àwọn eniyan gba agbára kún agbára wọn, kí wọ́n súnmọ́ ìtòsí, kí wọ́n sọ tẹnu wọn, ẹ jẹ́ kí á pàdé ní ilé ẹjọ́. “Ta ló gbé ẹnìkan dìde ní ìhà ìlà oòrùn? Tí ó ń ṣẹgun ní ibikíbi tí ó bá fẹsẹ̀ tẹ̀? Ta ló fi àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́ tí ó fi lè tẹ àwọn ọba mọ́lẹ̀? Idà rẹ̀ gé wọn bí eruku, ọfà rẹ̀ sì tú wọn ká bí àgékù koríko. A máa lépa wọn, a sì máa kọjá wọn láìléwu, ní ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tẹ̀ rí. Ta ló ṣe èyí? Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni? Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀? Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn. “Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù bà wọ́n, gbogbo òpin ayé gbọ̀n rìrì wọ́n ti súnmọ́ tòsí, wọ́n ti dé. Olukuluku ń ran ẹnìkejì rẹ̀ lọ́wọ́, ó ń sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ṣara gírí.’ Agbẹ́gilére ń gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú ẹni tí ń fi òòlù lu irin ń kí ẹni tí ń dán irin tí wọ́n ti rọ, Ó ń wí pé: ‘Òjé tí a fi jó o dára.’ Wọ́n kàn án ní ìṣó, ó le dáradára, kò le mì. “Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi, Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn, ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi. Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé, tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ, mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́, mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’ Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ. N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́; ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró. “Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ run ni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú. Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán, wọn óo sì ṣègbé. O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì, o kò ní rí wọn. Àwọn tí ó gbógun tì ọ́ yóo di òfo patapata. Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ, ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, èmi ni mo sọ fún ọ pé kí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.” Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín.

Isa 41:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú mi ẹ̀yin erékùṣù! Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tún agbára wọn ṣe! Jẹ́ kí wọn wá síwájú kí wọn sọ̀rọ̀: Jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́. “Ta ni ó ti ru ẹnìkan sókè láti ìlà-oòrùn wá, tí ó pè é ní olódodo sí iṣẹ́ tirẹ̀? Ó gbé àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájú rẹ̀. Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀, láti kù ú ní ìyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀. Ó ń lépa wọn ó sì ń kọjá ní àlàáfíà, ní ojú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí. Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé, tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe? Èmi OLúWA pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọn àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.” Àwọn erékùṣù ti rí i wọ́n bẹ̀rù; ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì. Wọ́n súnmọ́ tòsí wọ́n sì wá síwájú Èkínní ran èkejì lọ́wọ́ ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé “Jẹ́ alágbára!” Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú, àti ẹni tí ó fi òòlù dán mú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú. Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, “Ó dára.” Ó fi ìṣó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀. “Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi, Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn, ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi, mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé, láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́. Èmi wí pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;’ Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi. “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà; àwọn tó ń bá ọ jà yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ kì yóò rí wọn. Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́ yóò dàbí ohun tí kò sí. Nítorí Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù; Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni OLúWA wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.