Isa 37:1-20

Isa 37:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, nigbati Hesekiah ọba gbọ́, o fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ bora, o si lọ sinu ile Oluwa. O si ran Eliakimu, ti o ṣe olutọju ile, ati Ṣebna akọwe, ati awọn agba alufa ti nwọn fi aṣọ ọ̀fọ bora, sọdọ Isaiah woli, ọmọ Amosi. Nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Hesekiah wi, Oni jẹ ọjọ wahalà, ati ibawi, ati ẹgàn: nitori awọn ọmọ de igbà ibí, agbara kò si si lati bí wọn. Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ ọ̀rọ Rabṣake, ẹniti oluwa rẹ̀ ọba Assiria ti rán lati gàn Ọlọrun alãyè, yio si ba ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́ wi: nitorina gbe adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù. Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Hesekiah ọba wá sọdọ Isaiah. Isaiah si wi fun wọn pe, Bayi ni ki ẹ wi fun oluwa nyin, pe, Bayi ni Oluwa wi, Máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ ti iwọ ti gbọ́, nipa eyiti awọn iranṣẹ ọba Assiria ti fi sọ̀rọ buburu si mi. Wò o, emi o fi ẽmi kan sinu rẹ̀, on o si gbọ́ iró kan, yio si pada si ilu on tikalarẹ̀; emi o si mu ki o ti ipa idà ṣubu ni ilẹ on tikalarẹ̀. Bẹ̃ni Rabṣake padà, o si ba ọba Assiria mba Libna jagun: nitori ti o ti gbọ́ pe o ti kuro ni Lakiṣi. O si gbọ́ a nwi niti Tirhaka ọba Etiopia, pe, O mbọ̀ wá ba iwọ jagun. Nigbati o si gbọ́, o rán awọn ikọ̀ lọ sọdọ Hesekiah, wipe, Bayi ni ki ẹ wi fun Hesekiah ọba Juda, pe, Má jẹ ki Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ gbẹkẹle, ki o tàn ọ jẹ, wipe, A kì yio fi Jerusalemu le ọba Assiria lọwọ. Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si ilẹ gbogbo bi nwọn ti pa wọn run patapata: a o si gbà iwọ bi? Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun bi? bi Gosani, ati Harani ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti nwọn ti wà ni Telassari? Nibo ni ọba Hamati wà, ati ọba Arfadi, ati ọba ilu Sefarfaimu, Hena, ati Ifa? Hesekiah si gbà iwe na lọwọ awọn ikọ̀, o si kà a: Hesekiah si gòke lọ si ile Oluwa, o si tẹ́ ẹ siwaju Oluwa. Hesekiah si gbadura si Oluwa, wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikan, ninu gbogbo ijọba aiye: iwọ li o dá ọrun on aiye. Dẹti rẹ silẹ, Oluwa, ki o si gbọ́; ṣi oju rẹ, Oluwa, ki o si wò: si gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Senakeribu, ti o ranṣẹ lati kẹgàn Ọlọrun alãyè. Lõtọ ni, Oluwa, awọn ọba Assiria ti sọ gbogbo orilẹ-ède di ahoro, ati ilẹ wọn, Nwọn si ti sọ awọn òriṣa wọn sinu iná: nitori ọlọrun ki nwọn iṣe, ṣugbọn iṣẹ ọwọ́ enia ni, igi ati òkuta: nitorina ni nwọn ṣe pa wọn run. Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa lọwọ rẹ̀, ki gbogbo ijọba aiye le mọ̀ pe iwọ ni Oluwa, ani iwọ nikanṣoṣo.

Isa 37:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Hesekaya ọba gbọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì wọ inú ilé OLUWA lọ. Ó rán Eliakimu tí ń ṣàkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ilé ẹjọ́ ati àwọn àgbààgbà alufaa, wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n lọ sọ́dọ̀ wolii Aisaya, ọmọ Amosi. Wọ́n jíṣẹ́ fún un, wọ́n ní, “Hesekaya ní kí á sọ fún ọ pé: ‘Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ òní, ọjọ́ ìyà, ati ọjọ́ ẹ̀sín. Ọmọ ń mú aboyún, ó dé orí ìkúnlẹ̀, ṣugbọn kò sí agbára láti bíi. Ó ṣeéṣe kí OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbọ́ iṣẹ́ tí ọba Asiria rán Rabuṣake, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó wá fi Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà, kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀! Nítorí náà gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè kí o gbadura fún àwọn eniyan tí ó kù.’ ” Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Hesekaya ọba jíṣẹ́ fún Aisaya, Aisaya dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wí fún oluwa yín pé OLUWA ní: ‘Má bẹ̀rù nítorí ọ̀rọ̀ tí o gbọ́ tí iranṣẹ ọba Asiria sọ tí ó ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà. Ìwọ máa wò ó, n óo fi ẹ̀mí kan sí inú rẹ̀, yóo gbọ́ ìròyìn èké kan, yóo sì pada lọ sí ilẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí ó bá dé ilé n óo jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á.’ ” Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi, nítorí náà, ó lọ bá a níbi tí ó ti ń bá àwọn ará Libina jagun. Ibẹ̀ ni àwọn kan ti ròyìn fún ọba Asiria pé, Tirihaka ọba Etiopia ń bọ̀ wá gbógun tì í. Nígbà tí ó gbọ́, ó rán ikọ̀ lọ bá Hesekaya, ó ní: “Ẹ sọ fún Hesekaya ọba Juda pé kí ó má jẹ́ kí Ọlọrun rẹ̀ tí ó gbójú lé ṣì í lọ́nà kí ó sọ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu. Ṣebí Hesekaya ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Asiria ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n pa wọ́n run patapata. Ṣé Hesekaya rò pé a óo gba òun là ni? Ṣé àwọn oriṣa orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun gbà wọ́n sílẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Gosani ati Harani, Resefu ati àwọn ará Edẹni tí ń gbé Telasari? Ọba Hamati dà? Ọba Aripadi ńkọ́? Níbo ni ọba ìlú Sefafaimu ati ọba Hena ati ọba Ifa wà?” Hesekaya gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn ikọ̀ ọba Asiria, ó kà á. Nígbà tí ó kà á tán, ó gbéra, ó lọ sí ilé OLUWA, ó bá tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA, Hesekaya bá gbadura sí OLUWA, ó ní: “Ìwọ OLUWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israẹli, ìwọ tí ìtẹ́ rẹ wà lórí àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun gbogbo ìjọba ayé, ìwọ ni ó sì dá ọ̀run ati ayé. Dẹtí sílẹ̀ OLUWA, kí o gbọ́. La ojú rẹ, OLUWA, kí o máa wo nǹkan. Gbọ́ irú iṣẹ́ tí Senakeribu rán tí ó ń fi ìwọ Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà. Lóòótọ́ ni, OLUWA, pé àwọn ọba Asiria ti pa gbogbo orílẹ̀-èdè run tàwọn ti ilẹ̀ wọn, ati pé wọ́n ju oriṣa wọn sinu iná, nítorí pé wọn kì í ṣe Ọlọrun. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n, tí wọ́n fi igi ati òkúta ṣe, nítorí náà ni wọ́n ṣe lè pa wọ́n run. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ nìkan ni OLUWA.”

Isa 37:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ọba Hesekiah gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹmpili OLúWA lọ. Òun sì rán Eliakimu alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi. Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Hesekiah wí: ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ẹ̀gàn gẹ́gẹ́ bí ìgbà ìbí àwọn ọmọdé tí kò sì ṣí agbára láti bí wọn. Ó lè jẹ́ pé OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Asiria ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí OLúWA Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láààyè.” Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Hesekiah dé ọ̀dọ̀ Isaiah, Isaiah sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí OLúWA sọ nìyìí: Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Asiria tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀-òdì sí mi. Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ” Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Asiria ti fi Lakiṣi sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Libina jà. Ní àkókò yìí Sennakeribu gbọ́ ìròyìn kan pé Tirakah ará Kuṣi ọba Ejibiti ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ẹ sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘a kì yóò jọ̀wọ́ Jerusalẹmu fún ọba Asiria.’ Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó pa wọ́n run pátápátá. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí? Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gosani, Harani, Reṣefu àti àwọn ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari? Níbo ni ọba Hamati wà, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi tàbí Hena tàbí Iffa?” Hesekiah gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á. Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹmpili OLúWA ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLúWA. Hesekiah sì gbàdúrà sí OLúWA: OLúWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli, tí ó gúnwà láàrín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí i gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé. Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé. Tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ OLúWA, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ OLúWA, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Sennakeribu rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè. “Òtítọ́ ni OLúWA pé àwọn ọba Asiria ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán. Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe. Nísinsin yìí, ìwọ OLúWA, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, OLúWA ni Ọlọ́run.”