Isa 36:1-2
Isa 36:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si di igbati o ṣe li ọdun ikẹrinla Hesekiah ọba, Sennakeribu ọba Assiria wá dótì gbogbo ilu olodi Juda, o si kó wọn. Ọba Assiria si rán Rabṣake lati Lakiṣi lọ si Jerusalemu, ti on ti ogun nla, sọdọ Hesekiah ọba. O si duro lẹba idari omi abàta oke, li opopo pápa afọṣọ.
Isa 36:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọdún kẹrinla tí Ọba Hesekaya jọba, Senakeribu, ọba Asiria gbógun ti gbogbo ìlú olódi Juda, ó sì kó wọn. Ọba Asiria rán Rabuṣake (olórí ogun rẹ̀), pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun; láti Lakiṣi sí ọba Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọn dé ibi tí omi tí ń ṣàn wọ ìlú láti orí òkè tí ó wà ní ọ̀nà pápá alágbàfọ̀, wọ́n dúró níbẹ̀.
Isa 36:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba Hesekiah, Sennakeribu ọba Asiria kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda ó sì kó gbogbo wọn. Lẹ́yìn náà, ọba Asiria rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúṣàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá Alágbàfọ̀