Isa 31:1-9

Isa 31:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)

EGBE ni fun awọn ti o sọkalẹ lọ si Egipti fun iranlọwọ; ti nwọn gbẹkẹlẹ ẹṣin, ti nwọn gbiyèle kẹkẹ́, nitoriti nwọn pọ̀: nwọn si gbẹkẹle ẹlẹṣin nitoriti nwọn li agbara jọjọ; ṣugbọn ti nwọn kò wò Ẹni-Mimọ Israeli, nwọn kò si wá Oluwa! Ṣugbọn on gbọ́n pẹlu, o si mu ibi wá, kì yio si dá ọ̀rọ rẹ̀ padà: on si dide si ile awọn oluṣe buburu, ati si oluranlọwọ awọn ti nṣiṣẹ aiṣedede. Nitori enia li awọn ara Egipti, nwọn kì iṣe Ọlọrun; ẹran li awọn ẹṣin wọn, nwọn kì si iṣe ẹmi. Oluwa yio si nà ọwọ́ rẹ̀, ki ẹniti nràn ni lọwọ ba le ṣubu, ati ki ẹniti a nràn lọwọ ba lè ṣubu, gbogbo wọn o jùmọ ṣegbe. Nitori bayi li Oluwa ti wi fun mi pe, Gẹgẹ bi kiniun ati ẹgbọ̀rọ kiniun ti nkùn si ohun-ọdẹ rẹ̀, nigbati a npè ọpọlọpọ oluṣọ́-agutan jade wá si i, ti on kò bẹ̀ru ohùn wọn, ti kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ fun ariwo wọn: bẹ̃li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sọkalẹ wá lati jà lori okè-nla Sioni, ati lori oke kékèké rẹ̀. Gẹgẹ bi ẹiyẹ iti fi iyẹ́ apa ṣe, bẹ̃ni Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dabòbo Jerusalemu; ni didãbòbo o pẹlu yio si gbà o silẹ; ni rirekọja on o si dá a si. Ẹ yipadà si ẹniti ẹ ti nṣọ̀tẹ si gidigidi, ẹnyin ọmọ Israeli. Nitori li ọjọ na ni olukuluku enia yio jù ere fadaka rẹ̀, ati ere wura rẹ̀ nù, ti ọwọ́ ẹnyin tikara nyin ti ṣe fun ẹ̀ṣẹ fun nyin. Nigbana ni ara Assiria na yio ṣubú nipa idà, ti kì iṣe nipa idà ọkunrin, ati idà, ti ki iṣe ti enia yio jẹ ẹ: ṣugbọn on o sá kuro niwaju idà, awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ yio ma sìnrú. Apata rẹ̀ yio kọja lọ fun ẹ̀ru, awọn olori rẹ̀ yiọ bẹ̀ru asia na, ni Oluwa wi, ẹniti iná rẹ̀ wà ni Sioni, ati ileru rẹ̀ ni Jerusalemu.

Isa 31:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé! Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin; tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀, tí wọ́n gbójú lé ẹṣin nítorí pé wọ́n lágbára! Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli, wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ó gbọ́n, ó sì mọ ọ̀nà tí ó fi lè mú kí àjálù dé bá eniyan, kì í sọ̀rọ̀ tán, kó yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada. Ṣugbọn yóo dìde sí ìdílé àwọn aṣebi, ati àwọn tí ń ti àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn. Eniyan sá ni àwọn ará Ijipti, wọn kìí ṣe Ọlọrun. Ẹranko lásán sì ni ẹṣin wọn wọn kì í ṣe àǹjọ̀nnú. Bí OLUWA bá na ọwọ́, tí ó bá gbá wọn mú, ẹni tí ń ranni lọ́wọ́ yóo fẹsẹ̀ kọ, ẹni tí à ń ràn lọ́wọ́ yóo ṣubú; gbogbo wọn yóo sì jọ ṣègbé pọ̀. Nítorí OLUWA sọ fún mi pé, “Bí kinniun tabi ọmọ kinniun ti máa ń kùn lórí ẹran tí ó bá pa, tí kìí bìkítà fún igbe àwọn olùṣọ́ aguntan, tí wọ́n pera wọn jọ, tí wọn ń bọ̀, tí ẹ̀rù ariwo wọn kìí sìí bà á; bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo sọ̀kalẹ̀, yóo wá jà lórí òkè Sioni ati àwọn òkè tí ó yí Sioni ká. Bí àwọn ẹyẹ tií da ìyẹ́ bo ìtẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo Jerusalẹmu, yóo dáàbò bò ó, yóo sì gbà á sílẹ̀ yóo dá a sí, yóo sì yọ ọ́ kúrò ninu ewu.” Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ pada sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣàìgbọràn sí lọpọlọpọ. Nítorí pé ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo gbé àwọn ère fadaka ati ère wúrà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe sọnù, àwọn ère tí ó mú wọn dẹ́ṣẹ̀. Idà ni yóo pa Asiria, ṣugbọn kì í ṣe láti ọwọ́ eniyan; idà tí kò ní ọwọ́ eniyan ninu ni yóo pa á run. Yóo sá lójú ogun, a óo sì kó àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lọ máa ṣiṣẹ́ tipátipá. Ẹ̀rù yóo ba ọba Asiria, yóo sálọ. Ìpayà yóo mú kí àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ju àsíá sílẹ̀. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀, OLUWA tí iná rẹ̀ wà ní Sioni, tí ojú ààrò rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.

Isa 31:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́, tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn, ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì, tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ OLúWA. Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá; òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ. Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà, àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi. Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti wọn kì í ṣe Ọlọ́run; ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí. Nígbà tí OLúWA bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀, ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú; àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun. Èyí ni ohun tí OLúWA sọ fún mi: “Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀ bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀, ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè OLúWA àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu, Òun yóò dáàbò bò ó yóò sì tú u sílẹ̀ Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.” Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, Ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín ti ṣe. “Asiria yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá; idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n. Wọn yóò sì sá níwájú idà náà àti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe. Àpáta rẹ yóò kọjá lọ fún ẹ̀rù; àwọn olórí rẹ yóò bẹ̀rù asia náà,” ni OLúWA wí, ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Sioni, ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.