Isa 30:15-33

Isa 30:15-33 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitori bayi ni Oluwa Jehofah, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Ninu pipada on sisimi li a o fi gbà nyin là; ninu didakẹjẹ ati gbigbẹkẹle li agbara nyin wà; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Bẹ̃kọ; nitori ẹṣin li a o fi sá; nitorina li ẹnyin o ṣe sá: ati pe, Awa o gùn eyi ti o lè sare; nitorina awọn ti yio lepa nyin yio lè sare. Ẹgbẹrun yio sá ni ibawi ẹnikan; ni ibawi ẹni marun li ẹnyin o sá: titi ẹnyin o fi kù bi àmi lori oke-nla, ati bi asia lori oke. Nitorina ni Oluwa yio duro, ki o le ṣe ore fun nyin, ati nitori eyi li o ṣe ga, ki o le ṣe iyọ́nu si nyin: nitori Oluwa li Ọlọrun idajọ: ibukun ni fun gbogbo awọn ti o duro dè e. Nitori awọn enia Sioni yio gbe Jerusalemu, iwọ kì yio sọkun mọ: yio ṣanu fun ọ gidigidi nigbati iwọ ba nkigbe; nigbati on ba gbọ́ ọ, yio dá ọ lohùn. Oluwa yio si fi onjẹ ipọnju, ati omi inira fun nyin, awọn olukọ́ni rẹ kì yio sápamọ́ mọ, ṣugbọn oju rẹ yio ri olukọ́ni rẹ̀: Eti rẹ o si gbọ́ ọ̀rọ kan lẹhin rẹ, wipe, Eyiyi li ọ̀na, ẹ ma rin ninu rẹ̀, nigbati ẹnyin bá yi si apa ọtún, tabi nigbati ẹnyin bá yi si apa òsi. Ẹnyin o si sọ ibora ere fadaka nyin wọnni di aimọ́, ati ọṣọ́ ere wura didà nyin wọnni: iwọ o sọ wọn nù bi ohun-aimọ́, iwọ o si wi fun u pe, Kuro nihinyi. On o si rọ̀ òjo si irugbin rẹ ti iwọ ti fọ́n si ilẹ: ati onjẹ ibísi ilẹ, yio li ọrá yio si pọ̀: li ọjọ na ni awọn ẹran rẹ yio ma jẹ̀ ni pápa oko nla. Awọn akọ-malu pẹlu, ati awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ ti ntulẹ yio jẹ oko didùn, ti a ti fi kọ̀nkọsọ ati atẹ fẹ. Ati lori gbogbo oke-nla giga, ati lori gbogbo oke kékèké ti o ga, ni odò ati ipa-omi yio wà li ọjọ pipa nla, nigbati ile-iṣọ́ wọnni bá wó. Imọ́lẹ oṣupa yio si dabi imọ́lẹ õrun, imọ́lẹ õrun yio si ràn ni iwọ̀n igbà meje, bi imọ́lẹ ọjọ meje, li ọjọ ti Oluwa dí yiya awọn enia rẹ̀, ti o si ṣe àwotán ọgbẹ ti a ṣá wọn. Kiyesi i, orukọ Ọluwa mbọ̀ lati ọ̀na jijin wá, ibinu rẹ̀ si njo, ẹrù rẹ̀ si wuwo: ète rẹ̀ si kún fun ikannu, ati ahọn rẹ̀ bi ajonirun iná: Ẽmi rẹ̀ bi kikun omi, yio si de ãrin-meji ọrùn, lati fi kọ̀nkọsọ kù awọn orilẹ-ède: ijanu yio si wà li ẹ̀rẹkẹ́ awọn enia, lati mu wọn ṣina. Ẹnyin o li orin kan, gẹgẹ bi igbati a nṣe ajọ li oru; ati didùn inu, bi igbati ẹnikan fun fère lọ, lati wá si òke-nla Oluwa, sọdọ Apata Israeli. Oluwa yio si mu ki a gbọ́ ohùn ogo rẹ̀, yio si fi isọkalẹ apá rẹ̀ hàn pẹlu ikannu ibinu rẹ̀, ati pẹlu ọwọ́ ajonirun iná, pẹlu ifúnka, ati ijì, ati yinyín. Nitori nipa ohùn Oluwa li a o fi lù awọn ara Assiria bo ilẹ, ti o fi kùmọ lù. Ati nibi gbogbo ti paṣán ti a yàn ba kọja si, ti Oluwa yio fi lé e, yio ṣe pẹlu tabreti ati dùru: yio si fi irọ́kẹ̀kẹ ogun bá a jà. Nitori a ti yàn Tofeti lati igbà atijọ; nitõtọ, ọba li a ti pèse rẹ̀ fun; o ti ṣe e ki o jìn, ki o si gbòro: okiti rẹ̀ ni iná ati igi pupọ; emi Oluwa, bi iṣàn imí-ọjọ́ ntàn iná ràn a.

Isa 30:15-33 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní: “Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo rí ìgbàlà; bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun, ẹ óo lágbára. Ṣugbọn ẹ kọ̀. Ẹ sọ pé ó tì o, ẹ̀yin óo gun ẹṣin sálọ ni. Nítorí náà sísá ni ẹ óo sálọ. Ẹ sọ pé ẹṣin tí ó lè sáré ni ẹ óo gùn. Nítorí náà àwọn tí yóo máa le yín, wọn óo lè sáré gan-an ni. Ẹgbẹrun ninu yín yóo sá fún ẹyọ ọ̀tá yín kan, gbogbo yín yóo sì sá fún ẹyọ eniyan marun-un títí tí àwọn tí yóo kú ninu yín yóo fi dàbí igi àsíá lórí òkè. Wọn óo dàbí àsíá ati àmì lórí òkè.” Nítorí náà OLUWA ń dúró dè yín, ó ti ṣetán láti ṣàánú yín. Yóo dìde, yóo sì ràn yín lọ́wọ́. Nítorí Ọlọrun Olódodo ni OLUWA. Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i. Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.” Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!” OLUWA yóo sì fi òjò ibukun sí orí èso tí ẹ gbìn sinu oko, nǹkan ọ̀gbìn yín yóo sì so lọpọlọpọ. Ní àkókò náà, àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí yóo máa jẹ ní pápá oko yóo pọ̀. Àwọn mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ fí ń ṣe iṣẹ́ lóko yóo máa jẹ oko tí a fi iyọ̀ sí; tí a ti gbọn ìdọ̀tí kúrò lára rẹ̀. Omi yóo máa ṣàn jáde láti orí gbogbo òkè gíga ati gbogbo òkè ńlá, ní ọjọ́ tí ọpọlọpọ yóo kú, nígbà tí ilé ìṣọ́ bá wó lulẹ̀. Òṣùpá yóo mọ́lẹ̀ bí oòrùn; oòrùn yóo mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po meje, ní ọjọ́ tí OLUWA yóo bá di ọgbẹ́ àwọn eniyan rẹ̀, tí yóo sì wo ọgbẹ́ tí ó dá sí wọn lára sàn. Ẹ wo OLUWA tí ń bọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè, ó ń bọ̀ tìbínú-tìbínú; ninu èéfín ńlá tí ń lọ sókè. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kún fún ibinu; ahọ́n rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni run. Èémí rẹ̀ dàbí odò tí ó ṣàn kọjá bèbè rẹ̀ tí ó lè mu eniyan dé ọrùn. Yóo fi ajọ̀ ìparun jọ àwọn orílẹ̀-èdè, yóo sì fi ìjánu tí ń múni ṣìnà bọ àwọn eniyan lẹ́nu. Ẹ óo kọ orin kan bí orin alẹ́ ọjọ́ àjọ̀dún mímọ́, inú yín yóo sì dùn bíi ti ẹni tí ń jó ijó fèrè lọ sórí òkè OLUWA, àpáta Israẹli. OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ó lógo, yóo sì jẹ́ kí ẹ rí ọwọ́ rẹ̀ tí yóo fà yọ pẹlu ibinu ńlá ati ninu iná ajónirun; pẹlu ẹ̀fúùfù ati ìjì líle ati òjò yìnyín. Ìbẹ̀rù-bojo yóo mú àwọn ará Asiria nígbà tí wọ́n bá gbóhùn OLUWA, nígbà tí ó bá fi kùmọ̀ rẹ̀ lù wọ́n. Ìró ọ̀pá tí OLUWA yóo fi nà wọ́n yóo dàbí ìró aro ati dùùrù. OLUWA yóo dojú ogun kọ wọ́n. Nítorí pé a ti pèsè iná ìléru sílẹ̀ láti ìgbà àtijọ́ fún ọba Asiria; iná ńlá tí ń jó pẹlu ọpọlọpọ igi. Èémí OLUWA tó dàbí ìṣàn imí-ọjọ́ ni yóo ṣá iná sí i.

Isa 30:15-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí: “Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà, ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn. Ẹ̀yin wí pé, ‘bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’ Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá! Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’ Nítorí náà àwọn tí ń lé e yín yóò yára! Ẹgbẹ̀rún yóò sá nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan; nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún gbogbo yín lẹ ó sálọ, títí a ó fi yín sílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè, gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.” Síbẹ̀síbẹ̀ OLúWA sì fẹ́ ṣíjú àánú wò ọ́; ó dìde láti ṣàánú fún ọ. Nítorí OLúWA jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é! Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn. Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsì, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.” Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!” Òun yóò sì rọ òjò fún un yín sí àwọn irúgbìn tí ẹ gbìn sórí ilẹ̀, oúnjẹ tí yóò ti ilẹ̀ náà wá yóò ní ọ̀rá yóò sì pọ̀. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóò máa jẹ koríko ní pápá oko tútù tí ó tẹ́jú. Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi àmúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀. Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀mí wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò sàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré. Òṣùpá yóò sì tàn bí oòrùn, àti ìtànṣán oòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí OLúWA yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn. Kíyèsi i, orúkọ OLúWA ti òkèèrè wá pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kurukuru èéfín tí ó nípọn; ètè rẹ̀ kún fún ìbínú ahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun. Èémí rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára, tí ó rú sókè dé ọ̀run. Ó jọ àwọn orílẹ̀-èdè nínú kọ̀ǹkọ̀sọ̀; ó sì fi sí ìjánu ní àgbọ̀n àwọn ènìyàn láti ṣì wọ́n lọ́nà. Ẹ̀yin ó sì kọrin gẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́, ọkàn yín yóò yọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lú fèrè sí orí òkè OLúWA, àní sí àpáta Israẹli. OLúWA yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀ yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀ pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun, pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín. Ohùn OLúWA yóò fọ́ Asiria túútúú, pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀. Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí OLúWA bá gbé lé wọn pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀ yóò jẹ́ ti ṣaworo àti ti dùùrù, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun pẹ̀lú ìkùùkuu láti apá rẹ̀. A ti tọ́jú Tofeti sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́, a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba. Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jì tí ó sì fẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná; èémí OLúWA, gẹ́gẹ́ bí ìṣàn sulfuru ń jó ṣe mú un gbiná.