Isa 29:11-14
Isa 29:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iran gbogbo si dabi ọ̀rọ iwe kan fun nyin ti a dí, ti a fi fun ẹnikan ti o mọ̀ ọ kà, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, ti o si wipe, emi kò le ṣe e; nitori a ti dí i. A si fi iwe na fun ẹniti kò mọ̀ iwe, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, on si wipe, emi kò mọ̀ iwe. Nitorina Oluwa wipe, Niwọ̀n bi awọn enia yi ti nfi ẹnu wọn fà mọ mi, ti nwọn si nfi etè wọn yìn mi, ṣugbọn ti ọkàn wọn jìna si mi, ti nwọn si bẹru mi nipa ilana enia ti a kọ́ wọn. Nitorina, Kiye si i, emi o ma ṣe iṣẹ́ iyanu lọ lãrin awọn enia yi, ani iṣẹ iyanu ati ajeji: ọgbọ́n awọn ọlọgbọ́n wọn yio si ṣegbe, oye awọn amoye wọn yio si põra.
Isa 29:11-14 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo ìran yìí sì ru yín lójú, bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a fi èdìdì dì. Nígbà tí wọ́n gbé e fún ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.” Ó ní òun kò lè kà á nítorí pé wọ́n ti fi èdìdì dì í. Nígbà tí wọ́n gbé e fún ẹni tí kò mọ̀wé tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.” Ó ní òun kò mọ̀wé kà. OLUWA ní, “Nítorí pé ẹnu nìkan ni àwọn eniyan wọnyi fi ń súnmọ́ mi, ètè lásán ni wọ́n sì fi ń yìn mí; ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi. Òfin eniyan, tí wọn kọ́ sórí lásán, ni ìbẹ̀rù mi sì jẹ́ fún wọn. Nítorí náà n óo tún ṣe ohun ìyanu sí àwọn eniyan wọnyi, ohun ìyanu tí ó jọni lójú. Ọgbọ́n yóo parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu, ìmọ̀ràn yóo sì parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn níkùn.”
Isa 29:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.” Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.” Olúwa wí pé: “Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi. Ìsìn wọn si mi ni a gbé ka orí òfin tí àwọn ọkùnrin kọ́ ni. Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu; ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé, ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”