Isa 28:16-17
Isa 28:16-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina bayi li Oluwa Jehofah wi, pe, Kiyesi i, emi gbe okuta kan kalẹ ni Sioni fun ipilẹ, okuta ti a dán wò, okuta igun-ile iyebiye, ipilẹ ti o daju: ẹniti o gbagbọ kì yio sá. Idajọ li emi o fi le ẹsẹ pẹlu, ati ododo li emi o fi lé òṣuwọn: yinyín yio gbá ãbo eke lọ, omi o si kún bò ibi isasi mọlẹ.
Isa 28:16-17 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Wò ó! Èmi yóo ri òkúta ìpìlẹ̀ ilé kan mọ́lẹ̀ ní Sioni, yóo jẹ́ òkúta tí ó lágbára, òkúta igun ilé iyebíye, tí ó ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú: Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, ojú kò níí kán an. Ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ni n óo fi ṣe okùn ìwọnlẹ̀, òdodo ni n óo fi ṣe ìwọ̀n ògiri.”
Isa 28:16-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: “Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò, òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú; ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé kì yóò ní ìfòyà. Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òṣùwọ̀n àti òdodo òjé òṣùwọ̀n; yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́, omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀.