Isa 22:1-14
Isa 22:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ-ìmọ niti afonifoji ojuran. Kili o ṣe ọ nisisiyi, ti iwọ fi gùn ori ile lọ patapata? Iwọ ti o kún fun ìrukerudo, ilu aitòro, ilu ayọ̀: a kò fi idà pa awọn okú rẹ, bẹ̃ni nwọn kò kú li ogun. Gbogbo awọn alakoso rẹ ti jumọ sa lọ, awọn tafàtafà ti dì wọn ni igbekun: gbogbo awọn ti a ri ninu rẹ li a dì jọ, ti o ti sa lati okere wá. Nitorina li emi ṣe wipe, Mu oju kuro lara mi; emi o sọkun kikoro, má ṣe ãpọn lati tù mi ni inu, nitori iparun ti o ba ọmọbinrin enia mi. Nitori ọjọ wahála ni, ati itẹmọlẹ, ati idãmu, nipa Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun ni afonifoji ojuran, o nwó odi palẹ, o si nkigbe si oke-nla. Elamu ru apó pẹlu kẹkẹ́ enia ati ẹlẹṣin, Kiri si na asà silẹ. Yio si ṣe, afonifoji àṣayan rẹ yio kún fun kẹkẹ́, awọn ẹlẹṣin yio si tẹ́ ogun niha ẹnu odi. On si ri iboju Juda, iwọ si wò li ọjọ na ihamọra ile igbó. Ẹnyin ti ri oju-iho ilu Dafidi pẹlu, pe, nwọn pọ̀: ẹnyin si gbá omi ikudu isalẹ jọ. Ẹnyin ti kà iye ile Jerusalemu, awọn ile na li ẹnyin biwó lati mu odi le. Ẹnyin pẹlu ti wà yàra lãrin odi meji fun omi ikudu atijọ: ṣugbọn ẹnyin kò wò ẹniti o ṣe e, bẹ̃ni ẹ kò si buyìn fun ẹniti o ṣe e nigbãni, Ati li ọjọ na ni Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio pè lati sọkun, ati lati ṣọ̀fọ, ati lati fá ori, ati lati sán aṣọ ọ̀fọ. Si kiyesi i, ayọ̀ ati inu-didùn, pipa malũ, ati pipa agutan, jijẹ ẹran, ati mimu ọti-waini: ẹ jẹ ki a ma jẹ, ki a si ma mu; nitori ọla li awa o kú. Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ li eti mi, pe, Nitõtọ, a kì yio fọ̀ aiṣedede yi kuro lara nyin titi ẹnyin o fi kú, li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Isa 22:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Èyí ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àfonífojì ìran: Kí ni gbogbo yín ń rò tí ẹ fi gun orí òrùlé lọ, ẹ̀yin tí ìlú yín kún fún ariwo, tí ẹ jẹ́ kìkì ìrúkèrúdò ati àríyá? Gbogbo àwọn tí ó kú ninu yín kò kú ikú idà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú lójú ogun. Gbogbo àwọn ìjòyè ìlú yín parapọ̀ wọ́n sálọ, láì ta ọfà ni ọ̀tá mú wọn. Gbogbo àwọn tí wọn rí ni wọ́n mú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sá jìnnà. Nítorí náà, ni mo ṣe sọ pé, “Ẹ ṣíjú kúrò lára mi ẹ jẹ́ kí n sọkún, kí n dami lójú pòròpòrò, ẹ má ṣòpò pé ẹ óo rẹ̀ mí lẹ́kún, nítorí ìparun àwọn ará Jerusalẹmu, àwọn eniyan mi.” Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀, ọjọ́ ìrúkèrúdò ati ìdágìrì ati ìdàrúdàpọ̀, ní àfonífojì ìran. Ọjọ́ wíwó odi ìlú palẹ̀ ati igbe kíké láàrin àwọn òkè ńlá. Àwọn ọmọ ogun Elamu gbé ọfà wọn kọ́ èjìká, pẹlu kẹ̀kẹ́-ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun Kiri sì tọ́jú asà wọn. Àwọn àfonífojì dáradára yín kún fún kẹ̀kẹ́-ogun àwọn ẹlẹ́ṣin sì dúró sí ipò wọn lẹ́nu ibodè; ó ti tú aṣọ lára Juda. Ní ọjọ́ náà, ẹ gbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun ìjà tí ó wà ninu Ilé-Igbó, ẹ rí i pé ibi tí ògiri ìlú Dafidi ti sán pọ̀, ẹ sì gbá omi inú adágún tí ó wà ní ìsàlẹ̀ jọ. Ẹ ka iye ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu, ẹ sì wó àwọn kan palẹ̀ ninu wọn, kí ẹ lè rí òkúta tún odi ìlú ṣe. Ẹ wa kòtò sí ààrin ògiri mejeeji, Kí ẹ lè rí ààyè fa omi inú odò àtijọ́ sí. Ṣugbọn ẹ kò wo ojú ẹni tí ó ṣe ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bìkítà fún ẹni tí ó ṣètò rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá. Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun fi ìpè sóde pé, kí ẹ máa sọkún, kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀, kí ẹ fá orí yín, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora. Ṣugbọn dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń yọ̀, inú yín ń dùn. Ẹ̀ ń pa mààlúù, ẹ̀ ń pa aguntan, ẹ̀ ń jẹ ẹran, ẹ̀ ń mu ọtí waini. Ẹ̀ ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á jẹ, kí á mu! Nítorí pé lọ́la ni a óo kú.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi tó mi létí pé: “A kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì yín títí tí ẹ óo fi kú.”
Isa 22:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ Àfonífojì ìran: Kí ni ó ń dààmú yín báyìí, tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ? Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò, ìwọ ìlú àìtòrò òun rògbòdìyàn a kò fi idà pa àwọn òkú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú ní ojú ogun. Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ; a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà. Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀, lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wà lọ́nà jíjìn réré. Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi: jẹ́ kí n sọkún kíkorò. Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínú nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.” Olúwa, OLúWA àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan tí rúkèrúdò, rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ní Àfonífojì ìmọ̀, ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀ àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè. Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin, Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta. Àyànfẹ́ Àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú. Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò. Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náà sí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù, Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀, ìwọ ti tọ́jú omi sínú adágún ti ìsàlẹ̀. Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára. Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjì fún omi inú adágún àtijọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀ tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ó gbèrò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. OLúWA, àní OLúWA àwọn ọmọ-ogun, pè ọ́ ní ọjọ́ náà láti sọkún kí o sì pohùnréré, kí o tu irun rẹ dànù kí o sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora. Ṣùgbọ́n Wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà màlúù pípa àti àgùntàn pípa, ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu! “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu,” ni ẹ̀yin wí, “nítorí pé lọ́la àwa ó kú!” OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní OLúWA àwọn ọmọ-ogun.