Isa 20:4 - Compare All Versions

Isa 20:4 YBCV (Bibeli Mimọ)

Bẹ̃li ọba Assiria yio kó awọn ara Egipti ni igbèkun ati awọn ara Etiopia ni igbèkun, ọmọde ati arugbo, nihòho ati laibọ̀ bàta, ani ti awọn ti idí wọn nihòho, si itiju Egipti.

Isa 20:4 YCE (Yoruba Bible)

Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria yóo ṣe kó àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Kuṣi lẹ́rú, ati ọmọde ati àgbàlagbà wọn, ní ìhòòhò, láì wọ bàtà. A óo bọ́ aṣọ kúrò lára wọn, kí ojú ó lè ti Ijipti.

Isa 20:4 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọba Asiria yóò kó àwọn ìgbèkùn Ejibiti lọ ní ìhòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kuṣi, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí ìhòhò—bí àbùkù Ejibiti.