Isa 2:1-15

Isa 2:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀RỌ ti Isaiah ọmọ Amosi ri nipa Juda ati Jerusalemu. Yio si ṣe ni ọjọ ikẹhìn, a o fi òke ile Oluwa kalẹ lori awọn òke nla, a o si gbe e ga ju awọn òke kékèké lọ; gbogbo orilẹ-ède ni yio si wọ́ si inu rẹ̀. Ọ̀pọlọpọ enia ni yio si lọ, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si òke Oluwa, si ile Ọlọrun Jakobu; On o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa rẹ̀; nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu. On o si dajọ lãrin awọn orilẹ-ède, yio si ba ọ̀pọlọpọ enia wi: nwọn o fi idà wọn rọ ọbẹ-plau, nwọn o si fi ọ̀kọ wọn rọ dojé; orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède; bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ. Ara ile Jakobu, ẹ wá, ẹ jẹ́ ka rìn ninu imọlẹ Ọluwa. Nitorina ni iwọ ṣe kọ̀ awọn enia rẹ, ile Jakobu silẹ̀; nitoriti nwọn kún lati ìla ọ̀run wá, nwọn jẹ alafọ̀ṣẹ bi awọn ara Filistia, nwọn si nṣe inu didùn ninu awọn ọmọ alejò. Ilẹ wọn pẹlu kún fun fadakà ati wurà; bẹ̃ni kò si opin fun iṣura wọn; ilẹ wọn si kun fun ẹṣin, bẹ̃ni kò si opin fun kẹkẹ́ ogun wọn. Ilẹ wọn kún fun oriṣa pẹlu; nwọn mbọ iṣẹ ọwọ́ ara wọn, eyiti ika awọn tikalawọn ti ṣe. Enia lasan si foribalẹ, ẹni-nla si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; nitorina má ṣe darijì wọn. Wọ̀ inu apata lọ, ki o si fi ara rẹ pamọ ninu ekuru, nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀. A o rẹ̀ ìwo giga enia silẹ, a o si tẹ̀ ori igberaga enia ba, Oluwa nikanṣoṣo li a o gbe ga li ọjọ na. Nitori ọjọ Oluwa awọn ọmọ-ogun yio wà lori olukuluku ẹniti o rera, ti o si gberaga, ati lori olukuluku ẹniti a gbe soke, on li a o si rẹ̀ silẹ. Lori gbogbo igi kedari Lebanoni, ti o ga, ti a sì gbe soke, ati lori gbogbo igi-nla Baṣani. Ati lori gbogbo òke giga, ati lori gbogbo òke kékèké ti a gbe soke. Ati lori gbogbo ile-iṣọ giga ati lori gbogbo odi

Isa 2:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀rọ̀ tí Aisaya ọmọ Amosi sọ nípa Juda ati Jerusalẹmu nìyí: Ní ọjọ́ iwájú òkè ilé OLUWA yóo fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òkè tí ó ga jùlọ, a óo sì gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo wá sibẹ. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé: “Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ, kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀, kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wá ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.” Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; yóo sì bá ọpọlọpọ eniyan wí. Wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́, wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́. Ẹ̀yin ìdílé Jakọbu ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á rìn ninu ìmọ́lẹ̀ OLUWA. Nítorí o ti ta àwọn eniyan rẹ nù, àní, ìdílé Jakọbu. Nítorí pé àwọn aláfọ̀ṣẹ ará ìhà ìlà oòrùn pọ̀ láàrin wọn, àwọn alásọtẹ́lẹ̀ sì pọ̀ bíi ti àwọn ará Filistini, Wọ́n ti gba àṣà àwọn àjèjì. Wúrà ati fadaka kún ilẹ̀ wọn, ìṣúra wọn kò sì lópin. Ẹṣin kún ilẹ̀ wọn, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lóǹkà. Ilẹ̀ wọn kún fún oriṣa, wọ́n ń bọ iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, wọ́n ń wólẹ̀ fún ohun tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe tẹ ara rẹ̀ lórí ba tí ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀. Oluwa, máṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. Ẹ wọnú àpáta lọ, kí ẹ sì farapamọ́ sinu ilẹ̀. Ẹ sá fún ibinu OLUWA ati ògo ọlá ńlá rẹ̀. A óo rẹ ọlọ́kàn gíga eniyan sílẹ̀, a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀; OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà. Nítorí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀, tí yóo dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, ati àwọn ọlọ́kàn gíga, ati gbogbo nǹkan tí à ń gbéga. Yóo dojú kọ gbogbo igi Kedari ti Lẹbanoni, tí ó ga fíofío, ati gbogbo igi oaku ilẹ̀ Baṣani; ati gbogbo àwọn òkè ńláńlá, ati gbogbo òkè gíga, ati gbogbo ilé-ìṣọ́ gíga ati gbogbo odi tí ó lágbára

Isa 2:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ohun tí Isaiah ọmọ Amosi rí nípa Juda àti Jerusalẹmu: Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́ òkè tẹmpili OLúWA ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá OLúWA, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ OLúWA láti Jerusalẹmu. Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn. Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́. Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu, ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ OLúWA. OLúWA Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, ìwọ ilé Jakọbu. Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá, wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini, wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà. Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà, ìṣúra wọn kò sì ní òpin. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe. Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀ ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀, má ṣe dáríjì wọ́n. Wọ inú àpáta lọ, fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀ kúrò nínú ìpayà OLúWA, àti ògo ọláńlá rẹ̀! Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba, OLúWA nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà. OLúWA àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan ní ìpamọ́ fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀ sílẹ̀), nítorí gbogbo igi kedari Lebanoni, tó ga tó rìpó àti gbogbo óákù Baṣani, nítorí gbogbo òkè gíga ńláńlá àti àwọn òkè kéékèèkéé, fún ilé ìṣọ́ gíga gíga àti àwọn odi ìdáàbòbò