Isa 18:7
Isa 18:7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li akoko na ni a o mu ọrẹ wá fun Oluwa awọn ọmọ-ogun lati ọdọ awọn enia ti a nà ka, ti a si tẹju, ati enia ti o ni ibẹ̀ru lati igbayi ati titi lọ; orilẹ-ède ti o ni ipá ti o tẹ̀ ni mọlẹ, ilẹ ẹniti odò pupọ̀ pinyà, si ibi orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, oke giga Sioni.
Isa 18:7 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà, àwọn eniyan tí wọ́n ga, tí wọ́n sì ń dán, tí àwọn tí wọ́n súnmọ́ wọn, ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù, orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sì í máa ń ṣẹgun ọ̀tá, tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá, wọn óo mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní orí òkè Sioni, tí àwọn eniyan ń jọ́sìn ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun.
Isa 18:7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún OLúWA àwọn ọmọ-ogun láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo, orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè, ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ— a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Sioni, ibi tí orúkọ OLúWA àwọn ọmọ-ogun gbé wà.