Isa 18:2
Isa 18:2 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ti o rán awọn ikọ̀ li ọ̀na okun, ani ninu ọkọ̀ koriko odò, li oju odò, wipe, Lọ, ẹnyin onṣẹ ti o yara kánkan, si orilẹ-ède ti a nà ká ti a si tẹju, si enia ti o ni ibẹ̀ru lati igbayi ati titi lọ; orilẹ-ède ti o ni ipá, ti o si tẹ̀ ni mọlẹ, ilẹ ẹniti odò pupọ̀ pinyà!
Isa 18:2 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ó rán ikọ̀ lọ sí òkè odò Naili, tí wọ́n fẹní ṣọkọ̀ ojú omi. Ẹ lọ kíá, ẹ̀yin iranṣẹ ayára-bí-àṣá, ẹ lọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tí ara wọn ń dán, àwọn tí àwọn eniyan tí wọ́n súnmọ́ wọn ati àwọn tí ó jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù. Orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sìí máa ń ṣẹgun ọ̀tá, àwọn tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá.
Isa 18:2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe. Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára, sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀, sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri, orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè, tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.