Isa 18:1-7

Isa 18:1-7 Yoruba Bible (YCE)

Ó ṣe, ní òkè àwọn odò kan ní ilẹ̀ Sudani ibìkan wà tí àwọn ẹyẹ ti ń fò pẹ̀ẹ̀rẹ̀pẹ̀. Ẹni tí ó rán ikọ̀ lọ sí òkè odò Naili, tí wọ́n fẹní ṣọkọ̀ ojú omi. Ẹ lọ kíá, ẹ̀yin iranṣẹ ayára-bí-àṣá, ẹ lọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tí ara wọn ń dán, àwọn tí àwọn eniyan tí wọ́n súnmọ́ wọn ati àwọn tí ó jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù. Orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sìí máa ń ṣẹgun ọ̀tá, àwọn tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá. Gbogbo aráyé, ẹ̀yin tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àsíá sókè lórí àwọn òkè, ẹ wò ó, nígbà tí a bá fun fèrè ogun, ẹ gbọ́. Nítorí pé OLUWA sọ fún mi pé òun óo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wolẹ̀ láti ibi ibùgbé òun bí ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán gangan, ati bí ìkùukùu ninu ooru ìgbà ìkórè. Nítorí pé kí ó tó di ìgbà ìkórè, lẹ́yìn tí ìtànná àjàrà bá ti rẹ̀, tí ó di èso, tí àjàrà bẹ̀rẹ̀ sí gbó, tí ó ń pọ́n bọ̀, ọ̀tá yóo ti dòjé bọ àwọn ìtàkùn àjàrà, yóo sì gé gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ kúrò. Gbogbo wọn yóo wà nílẹ̀, wọn yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ orí òkè, ati àwọn ẹranko inú ìgbẹ́. Àwọn ẹyẹ yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn ẹranko yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ jẹ ní ìgbà òtútù. Ní àkókò náà, àwọn eniyan tí wọ́n ga, tí wọ́n sì ń dán, tí àwọn tí wọ́n súnmọ́ wọn, ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù, orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sì í máa ń ṣẹgun ọ̀tá, tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá, wọn óo mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní orí òkè Sioni, tí àwọn eniyan ń jọ́sìn ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun.

Isa 18:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú, ní àwọn ipadò Kuṣi, tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe. Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára, sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀, sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri, orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè, tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé, tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè, ẹ ó rí i, nígbà tí a bá fun fèrè kan ẹ ó gbọ́ ọ. Èyí ni ohun tí OLúWA sọ fún mi: “Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréré láti ibùgbé e mi wá, gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn, gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.” Nítorí, kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìrudí bá kún, nígbà tí ìtànná bá di èso àjàrà pípọ́n. Òun yóò sì fi dòjé rẹ́ ẹ̀ka tuntun, yóò sì mu kúrò, yóò sì gé ẹ̀ka lulẹ̀. A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá àti fún àwọn ẹranko búburú; àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò. Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún OLúWA àwọn ọmọ-ogun láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo, orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè, ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ— a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Sioni, ibi tí orúkọ OLúWA àwọn ọmọ-ogun gbé wà.