Isa 16:1-14
Isa 16:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ rán ọdọ-agutan si alakoso ilẹ lati Sela wá si aginju, si oke ọmọbinrin Sioni. Yio si ṣe, bi alarinkiri ẹiyẹ ti a le jade kuro ninu itẹ́-ẹiyẹ, bẹ̃ni ọmọbinrin Moabu yio ri ni iwọdò Arnoni. Ẹ gbìmọ, ẹ mu idajọ ṣẹ; ṣe ojiji rẹ bi oru li ãrin ọsángangan; pa awọn ti a le jade mọ́; máṣe fi isánsa hàn. Moabu, jẹ ki awọn isánsa mi ba ọ gbe, iwọ ma jẹ ãbo fun wọn li oju akoni: nitori alọnilọwọgbà de opin, akoni dasẹ̀, a pa awọn aninilara run kuro lori ilẹ. Ninu ãnu li a o si fi idi ilẹ mulẹ: yio si joko lori rẹ̀ li otitọ ninu agọ Dafidi, yio ma ṣe idajọ, yio si ma wá idajọ, yio si ma mu ododo yara kánkán. Awa ti gbọ́ ti igberaga Moabu; o gberaga pọju: ani ti irera rẹ̀, ati igberaga rẹ̀, ati ibinu rẹ̀; ihalẹ rẹ̀ asan ni. Nitorina ni Moabu yio hu fun Moabu, gbogbo wọn o hu: nitori ipilẹ Kir-haresi li ẹnyin o gbàwẹ; nitõtọ a lù wọn. Nitori igbẹ́ Heṣboni rọ, ati àjara Sibma: awọn oluwa awọn keferi ti ke pataki ọ̀gbin rẹ̀ lu ilẹ, nwọn tàn de Jaseri, nwọn nrìn kakiri aginjù: ẹka rẹ̀ nà jade, nwọn kọja okun. Nitorina emi o pohùnrére ẹkun, bi ẹkun Jaseri, àjara Sibma: emi o fi omije mi rin ọ, iwọ Heṣboni, ati Eleale: nitori ariwo nla ta lori èso-igi ẹ̃rùn rẹ, ati lori ikore rẹ. A si mu inu-didun kuro, ati ayọ̀ kuro ninu oko ti nso eso ọ̀pọlọpọ; orin kì yio si si mọ ninu ọgbà-àjara, bẹ̃ni kì yio si ihó-ayọ̀ mọ: afọnti kì yio fọn ọti-waini mọ ninu ifọnti wọn, emi ti mu ariwo dá. Nitorina inu mi yio dún bi harpu fun Moabu, ati ọkàn mi fun Kir-haresi. Yio si ṣe, nigbati a ba ri pe ãrẹ̀ mú Moabu ni ibi giga, ni yio wá si ibi-mimọ́ rẹ̀ lati gbadura; ṣugbọn kì yio bori. Eyi li ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti Moabu lati igbà na wá. Ṣugbọn nisisiyi Oluwa ti sọ̀rọ, wipe, Niwọn ọdun mẹta, gẹgẹ bi ọdun alagbaṣe, a o si kẹgàn ogo Moabu, pẹlu gbogbo ọ̀pọlọpọ nì: awọn iyokù yio kere, kì yio si li agbara.
Isa 16:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n ti kó àgbò láti Sela, ní ọ̀nà aṣálẹ̀, wọ́n fi ranṣẹ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, ní òkè Sioni. Àwọn ọmọbinrin Moabu dúró létí odò Anoni, wọ́n ń rìn síwá, sẹ́yìn, wọ́n ń lọ sókè, sódò, bí ọmọ ẹyẹ tí a lé kúrò ninu ìtẹ́. “Gbà wá ní ìmọ̀ràn, máa ṣe ẹ̀tọ́ fún wa. Fi òjìji rẹ dáàbò bò wá, kí ara lè tù wá lọ́sàn-án gangan, bí ẹni pé alẹ́ ni. Dáàbò bo àwọn tí a lé jáde; má tú àṣírí ẹni tí ń sálọ. Jẹ́ kí àwọn tí a lé jáde ní Moabu, máa gbé ààrin yín. Dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn apanirun.” Nígbà tí aninilára kò bá sí mọ́ tí ìparun bá dópin, tí atẹnimọ́lẹ̀ bá ti kúrò ní ilẹ̀ náà. Nígbà náà a óo fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ pẹlu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo yóo jókòó lórí ìtẹ́ náà, Yóo dúró lórí òtítọ́ ní ìdílé Dafidi. A ti gbọ́ ìròyìn ìgbéraga Moabu, bí ó ṣe ń ṣe àfojúdi tí ó sì ń sọ ìsọkúsọ: ṣugbọn lásán ni ìgbéraga rẹ̀. Nítorí náà, kí Moabu máa pohùnréré ẹkún, kí gbogbo eniyan máa sun ẹkún arò ní Moabu. Wọn óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nígbà tí wọn ba ranti àkàrà Kiri Heresi, tí ó ní èso àjàrà ninu. Gbogbo oko ni ó rọ ní Heṣiboni; bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbà Sibuma: àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lulẹ̀, èyí tí ó tàn kálẹ̀ dé Jaseri títí dé inú aṣálẹ̀. Ìtàkùn rẹ̀ tàn kálẹ̀, wọ́n kọjá sí òdìkejì òkun. Nítorí náà mo sọkún fún ọgbà àjàrà Sibuma bí mo ṣe sọkún fún Jaseri; mo sì sọkún nítorí Heṣiboni ati Eleale, mo sọkún, omi ń dà lójú mi pòròpòrò nítorí gbogbo ìkórè yín, ati èso oko yín ni ogun ti kó lọ. Wọ́n ti kó ayọ̀ ati ìdùnnú lọ kúrò ninu oko eléso; ẹnikẹ́ni kò kọrin bẹ́ẹ̀ ni kò sí ariwo híhó ninu ọgbà àjàrà wọn. Kò sí àwọn tí ó ń pọn ọtí ninu rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ariwo àwọn tí ń pọn ọtí mọ́. Nítorí náà, ẹ̀mí mi kọrin arò bíi ti dùùrù fún Moabu, ọkàn mi kérora, fún Moabu ati Kiri Heresi. Nígbà tí Moabu bá wá siwaju, tí ó fi gbogbo agbára gbadura ninu ilé oriṣa rẹ̀, títí ó fi rẹ̀ ẹ́, adura rẹ̀ kò ní gbà. Ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti kọ́ sọ nípa Moabu tẹ́lẹ̀ nìyí. Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA ní, “Nígbà tí a óo fi rí ọdún mẹta, tíí ṣe iye ọdún alágbàṣe, a óo ti sọ ògo Moabu di ilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan inú rẹ̀ pọ̀, àwọn díẹ̀ ni yóo ṣẹ́kù, àárẹ̀ yóo sì ti mú wọn.”
Isa 16:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, láti Sela, kọjá ní aginjù, lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Sioni. Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu ní àwọn ìwọdò Arnoni. “Fún wa ní ìmọ̀ràn ṣe ìpinnu fún wa. Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru, ní ọ̀sán gangan. Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́, má ṣe fi àwọn aṣàtìpó han Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ, jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.” Aninilára yóò wá sí òpin, ìparun yóò dáwọ́ dúró; òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀. Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀, ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀ ẹnìkan láti ilé Dafidi wá. Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́, yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo. Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu, ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge, gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo. Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu, wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu. Sọkún kí o sì banújẹ́ fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti. Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ, bákan náà ni àjàrà Sibma rí. Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀, èyí tí ó ti fà dé Jaseri ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù. Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde, ó sì lọ títí ó fi dé Òkun. Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún, fún àwọn àjàrà Sibma. Ìwọ Heṣboni, Ìwọ Eleale, mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú! Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró. Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò nínú ọgbà-igi eléso rẹ; kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí kígbe nínú ọgbà àjàrà: ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí, nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe. Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù, àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti. Nígbà tí Moabu farahàn ní ibi gíga rẹ̀, ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán; Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà òfo ni ó jásí. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLúWA ti sọ nípa Moabu. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí OLúWA wí pé: “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”