Isa 14:3-14
Isa 14:3-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Yio si ṣe li ọjọ ti Oluwa yio fun ọ ni isimi kuro ninu ibanujẹ rẹ, ati kuro ninu ijaiya rẹ, ati kuro ninu oko-ẹru lile nibiti a ti mu ọ sìn, Ni iwọ o si fi ọba Babiloni ṣẹ̀fẹ yi, ti iwọ o si wipe, Aninilara nì ha ti ṣe dakẹ! alọnilọwọgbà wura dakẹ! Oluwa ti ṣẹ ọpá oluṣe-buburu, ati ọpá-alade awọn alakoso. Ẹniti o fi ibinu lù awọn enia lai dawọ duro, ẹniti o fi ibinu ṣe akoso awọn orilẹ-ède, li a nṣe inunibini si, lai dẹkun. Gbogbo aiye simi, nwọn si gbe jẹ: nwọn bú jade ninu orin kikọ. Nitõtọ, igi firi nyọ̀ ọ, ati igi kedari ti Lebanoni, wipe, Lati ìgba ti iwọ ti dubulẹ, kò si akegi ti o tọ̀ wa wá. Ipò-okú lati isalẹ wá mì fun ọ lati pade rẹ li àbọ rẹ: o rú awọn okú dide fun ọ, ani gbogbo awọn alakoso aiye; o ti gbe gbogbo ọba awọn orilẹ-ède dide kuro lori itẹ wọn. Gbogbo wọn o dahùn, nwọn o si wi fun ọ pe, Iwọ pẹlu ti di ailera gẹgẹ bi awa? iwọ ha dabi awa? Ogo rẹ li ati sọ̀kalẹ si ipò-okú, ati ariwo durù rẹ: ekòlo ti tàn sabẹ rẹ, idin si bò ọ mọ ilẹ. Bawo ni iwọ ti ṣe ṣubu lati ọrun wá, Iwọ Lusiferi, iràwọ owurọ! bawo li a ti ṣe ke ọ lu ilẹ, iwọ ti o ti ṣẹ́ awọn orilẹ-ède li apa! Nitori iwọ ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi o goke lọ si ọrun, emi o gbe itẹ mi ga kọja iràwọ Ọlọrun: emi o si joko lori oke ijọ enia ni iha ariwa: Emi o goke kọja giga awọsanma: emi o dabi ọga-ogo jùlọ.
Isa 14:3-14 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí OLUWA bá fun yín ní ìsinmi kúrò ninu làálàá ati rògbòdìyàn ati iṣẹ́ àṣekára tí wọn ń fi tipá mu yín ṣe, ẹ óo kọrin òwe bú ọba Babiloni pé: “Agbára aninilára ti pin ìpayà ojoojumọ ti dópin. OLUWA ti ṣẹ́ ọ̀pá àṣẹ àwọn ẹni ibi, ati ọ̀pá àṣẹ àwọn olórí tí wọn ń fi ibinu lu àwọn eniyan láì dáwọ́ dúró, tí wọn ń fi ibinu ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ń ṣe inúnibíni lemọ́lemọ́. Gbogbo ayé wà ní ìsinmi ati alaafia wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin ayọ̀. Àwọn igi Sipirẹsi ń yọ̀ yín; àwọn igi Kedari ti Lẹbanoni sì ń sọ pé, ‘Láti ìgbà tí a ti rẹ ọba Babiloni sílẹ̀, kò sí agégi kan tí ó wá dààmú wa mọ́.’ “Isà òkú ti lanu sílẹ̀ láti pàdé rẹ bí o bá ti ń dé. Ó ta àwọn òkú ọ̀run jí láti kí ọ, àwọn tí wọ́n ṣe pataki ní àkókò wọn, Ó gbé gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn. Gbogbo wọn yóo wí fún ọ pé, ‘Àárẹ̀ ti mu yín gẹ́gẹ́ bí ó ti mú àwa náà. Ẹ ti dàbí i wa. A ti fa ògo yín ati ohùn hapu yín sinu isà òkú. Ìdin di ibùsùn tí ẹ sùn lé lórí àwọn kòkòrò ni ẹ sì fi bora bí aṣọ.’ “Ọba Babiloni, wò ó! Bí o ti jábọ́ láti ojú ọ̀run, ìwọ tí o dàbí ìràwọ̀ òwúrọ̀! Wò ó bí a ti sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀, ìwọ tí o ti pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè run rí. Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘N óo gòkè dé ọ̀run, n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run; n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan, ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré. N óo gòkè kọjá ìkùukùu ojú ọ̀run, n óo wá dàbí Olodumare.’
Isa 14:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ tí OLúWA yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé: Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin! Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí! OLúWA ti dá ọ̀pá ìkà náà, ọ̀pá àwọn aláṣẹ, èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀ pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró, nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin. Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà, wọ́n bú sí orin. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn igi kedari ti Lebanoni ń yọ̀ lórí rẹ wí pé, “Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí, kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.” Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀ ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè. Gbogbo wọn yóò dáhùn, wọn yóò wí fún ọ wí pé, “Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ìwọ náà ti dàbí wa.” Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì, pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ, àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀. Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá, ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà! A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé Ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí! Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé, “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run; Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run, Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́. Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀; Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.”