Isa 13:17-22
Isa 13:17-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiyesi i, emi o gbe awọn ara Media dide si wọn, ti ki yio ka fadakà si; bi o si ṣe ti wura, nwọn ki yio ni inu didùn si i. Ọrun wọn pẹlu yio fọ́ awọn ọdọmọkunrin tũtũ; nwọn ki yio ṣãnu fun ọmọ-inu: oju wọn kì yio dá ọmọde si. Ati Babiloni, ogo ijọba gbogbo, ẹwà ogo Kaldea, yio dabi igbati Ọlọrun bi Sodomu on Gomorra ṣubu. A kì yio tẹ̀ ẹ dó mọ, bẹ̃ni a kì yio si gbe ibẹ̀ mọ lati irandiran: bẹ̃ni awọn ara Arabia kì yio pagọ nibẹ mọ; bẹ̃ni awọn oluṣọ-agutan kì yio kọ́ agbo wọn nibẹ mọ. Ṣugbọn ẹranko igbẹ yio dubulẹ nibẹ; ile wọn yio si kun fun òwiwí, abo ogòngo yio ma gbe ibẹ, ọ̀rọ̀ yio si ma jo nibẹ. Awọn ọ̀wawa yio si ma ke ninu ãfin wọn, ati dragoni ninu gbọ̀ngàn wọn daradara: ìgba rẹ̀ si sunmọ etile, a kì yio si fa ọjọ rẹ̀ gùn.
Isa 13:17-22 Yoruba Bible (YCE)
Wò ó! N óo rú àwọn ará Media sókè sí wọn, àwọn tí wọn kò bìkítà fún fadaka bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ka wúrà sí. Wọn óo wá bá Babiloni jà. Wọn yóo fi ọfà pa àwọn ọdọmọkunrin, wọn kò ní ṣàánú oyún inú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣàánú àwọn ọmọde. Babiloni, ìwọ tí o lógo jù láàrin gbogbo ìjọba ayé, ìwọ tí o jẹ́ ẹwà ati ògo àwọn ará Kalidea, yóo dàbí Sodomu ati Gomora, nígbà tí Ọlọrun pa wọ́n run. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ láti ìran dé ìran, àwọn ará Arabia kankan kò ní pa àgọ́ sibẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn darandaran kankan kò ní jẹ́ kí agbo aguntan wọn sinmi níbẹ̀. Ṣugbọn àwọn ẹranko ní yóo máa sùn níbẹ̀ ilé rẹ̀ yóo sì kún fún ẹyẹ òwìwí, ògòǹgò yóo máa gbè ibẹ̀ ẹhànnà òbúkọ yóo sì máa ta pọ́núnpọ́nún káàkiri ibẹ̀. Àwọn ìkookò yóo máa ké ninu ilé ìṣọ́ rẹ̀, ààfin rẹ̀ yóo di ibùgbé àwọn ajáko, àkókò rẹ̀ súnmọ́ etílé, ọjọ́ rẹ̀ kò sì ní pẹ́ mọ́.
Isa 13:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn, àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà. Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀; wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdé tàbí kí wọn ṣíjú àánú wo àwọn ọmọdé. Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra. A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́ tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran; Ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́, olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀, àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn, níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri. Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn, àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.