Isa 13:1-16
Isa 13:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ-ìmọ niti Babiloni ti Isaiah ọmọ Amosi ri. Ẹ gbe ọpágun soke lori oke giga, ẹ kọ si wọn, ẹ juwọ, ki nwọn ba le lọ sinu ẹnu-odi awọn ọlọla. Emi ti paṣẹ fun awọn temi ti a yà si mimọ́, emi ti pe awọn alagbara mi pẹlu fun ibinu mi, ani awọn ti nwọn yọ̀ ninu ọlanla mi. Ariwo ọ̀pọlọpọ lori oke, gẹgẹ bi ti enia pupọ̀: ariwo rudurudu ti ijọba awọn orilẹ-ède, ti a kojọ pọ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun gbá ogun awọn ọmọ-ogun jọ. Nwọn ti ilẹ okerè wá, lati ipẹkun ọrun, ani, Oluwa, ati ohun-elò ibinu rẹ̀, lati pa gbogbo ilẹ run. Ẹ hu; nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ; yio de bi iparun lati ọdọ Olodumare wá. Nitorina gbogbo ọwọ́ yio rọ, ọkàn olukuluku enia yio si di yiyọ́. Nwọn o si bẹ̀ru: irora ati ikãnu yio dì wọn mu; nwọn o wà ni irora bi obinrin ti nrọbi: ẹnu yio yà ẹnikan si ẹnikeji rẹ̀; oju wọn yio dabi ọwọ́-iná. Kiyesi i, ọjọ Oluwa mbọ̀ wá, o ni ibi ti on ti ikannú ati ibinu gbigboná, lati sọ ilẹ na di ahoro: yio si pa awọn ẹlẹṣẹ run kuro ninu rẹ̀. Nitori awọn iràwọ ọrun, ati iṣùpọ iràwọ inu rẹ̀ kì yio tàn imọlẹ wọn: õrun yio ṣu okùnkun ni ijadelọ rẹ̀, oṣùpa kì yio si mu ki imọlẹ rẹ̀ tàn. Emi o si bẹ̀ ibi wò lara aiye, ati aiṣedẽde lara awọn enia buburu; emi o si mu ki igberaga awọn agberaga ki o mọ, emi o si mu igberaga awọn alagbara rẹ̀ silẹ. Emi o mu ki ọkunrin kan ṣọwọ́n ju wura lọ; ani enia kan ju wura Ofiri daradara. Nitorina emi o mu ọrun mì titi, ilẹ aiye yio si ṣipò rẹ̀ pada, ninu ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀. Yio si dabi abo agbọ̀nrin ti a nlepa, ati bi agutan ti ẹnikan kò gbajọ: olukuluku wọn o yipada si enia rẹ̀, olukuluku yio si sa si ilẹ rẹ̀. Ẹnikẹni ti a ri li a o gun li agunyọ; ẹnikẹni ti o si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ wọn yio ti ipa idà ṣubu. Ọmọ wọn pẹlu li a o fọ́ tũtu loju ara wọn; a o si kó wọn ni ile, a o si fi agbara bà obinrin wọn jẹ́
Isa 13:1-16 Yoruba Bible (YCE)
Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Babiloni: Ẹ ta àsíá ní orí òkè gíga, ẹ gbóhùn sókè sí wọn. Ẹ juwọ́, kí àwọn ológun gba ẹnu ibodè àwọn ọlọ́lá wọlé. Èmi pàápàá ti pàṣẹ fún àwọn tí mo yà sọ́tọ̀, mo ti pe àwọn akọni mi, tí mo fi ń yangàn, láti fi ibinu mi hàn. Gbọ́ ariwo lórí òkè, bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, gbọ́ ariwo ìdàrúdàpọ̀ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ń péjọ pọ̀! OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ń kó àwọn ọmọ ogun jọ fún ogun. Wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè, láti ìpẹ̀kun ayé. OLUWA ń bọ̀ pẹlu àwọn ohun ìjà ibinu rẹ̀, tí yóo fi pa gbogbo ayé run. Ẹ pohùnréré ẹkún, nítorí pé ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé, yóo dé bí ìparun láti ọwọ́ Olodumare. Nítorí náà ọwọ́ gbogbo eniyan yóo rọ, ọkàn gbogbo eniyan yóo rẹ̀wẹ̀sì; ẹnu yóo sì yà wọ́n. Ìpayà ati ìrora yóo mú wọn, wọn yóo wà ninu ìrora bí obinrin tí ó ń rọbí; wọn óo wo ara wọn tìyanu-tìyanu, ojú yóo sì tì wọ́n. Wò ó! Ọjọ́ OLUWA dé tán, tìkàtìkà pẹlu ìrúnú ati ibinu gbígbóná láti sọ ayé di ahoro, ati láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run. Nítorí àgbájọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóo kọ̀, wọn kò ní tan ìmọ́lẹ̀. Oòrùn yóo ṣókùnkùn nígbà tí ó bá yọ, òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀. N óo fìyà jẹ ayé nítorí iṣẹ́ ibi rẹ̀, n óo sì jẹ àwọn ìkà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo fòpin sí àṣejù àwọn onigbeeraga, n óo rẹ ìgbéraga àwọn tí kò lójú àánú sílẹ̀. N óo sọ eniyan di ohun tí ó ṣọ̀wọ́n ju wúrà dáradára lọ, irú eniyan yóo ṣọ̀wọ́n ju wúrà ilẹ̀ Ofiri lọ. Nítorí náà n óo mú kí àwọn ọ̀run wárìrì ayé yóo sì mì tìtì tóbẹ́ẹ̀ tí yóo sún kúrò ní ipò rẹ̀, nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ọjọ́ tí inú rẹ̀ bá ru. Eniyan yóo dàbí àgbọ̀nrín tí ọdẹ ń lé, ati bí aguntan tí kò ní olùṣọ́; olukuluku yóo doríkọ ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, wọn óo sì sá lọ sí ilẹ̀ wọn. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí, wọn óo fi ọ̀kọ̀ gún un pa, ẹni tí ọwọ́ bá tẹ̀, idà ni wọ́n ó fi pa á. A óo so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ lójú wọn, a óo kó ilé wọn, a óo sì bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀ pẹlu agbára.
Isa 13:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Babeli èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí: Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu, kígbe sí wọn, pè wọ́n láti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi, mo ti pe àwọn jagunjagun mi láti gbé ìbínú mi jáde àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi. Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè, gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba, gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè! OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ àwọn jagunjagun fún ogun. Wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn réré, láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá OLúWA pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀, láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà run. Ẹ hu, nítorí ọjọ́ OLúWA súnmọ́ tòsí, yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ. Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ, ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì. Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú, ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú, wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí. Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà ojú wọn á sì gbinájẹ. Kíyèsi i, ọjọ́ OLúWA ń bọ̀ ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná— láti sọ ilẹ̀ náà dahoro, àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn. Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn. Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀, àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀. Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn ju ojúlówóo wúrà lọ, yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ. Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì; ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀ láti ọwọ́ ìbínú OLúWA àwọn ọmọ-ogun, ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ. Gẹ́gẹ́ bí egbin tí à ń dọdẹ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu, gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú. Àwọn ọ̀dọ́mọdé wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn, gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kó àwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀.